Faith Adebọla, Eko
Titi ni awọn ilẹkun ile-ẹjọ gbogbo yoo wa nipinlẹ Eko bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, titi di ọjọ karun-un, oṣu ki-in-ni, ọdun to n bọ.
Adajọ agba ipinlẹ Eko, Onidaajọ Kareem Alogba, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti Abilekọ Busọla Okunọla fi lede lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Atẹjade naa ni yatọ si bi ẹjọ kan ba jẹ pajawiri to kọja bẹẹ, eyi ti adajọ ti wọn ba yan fun un yoo bojuto laaye ara ẹ, gbogbo ẹjọ ati iwe ẹsun to wa nilẹ yoo ni lati duro di oṣu ki-in-ni, ọdun 2021, ti iṣẹ idajọ yoo bẹrẹ lakọtun.
Alogba ni ẹsẹ ofin kọkandinlaaadọta, isọri kẹrin, iwe ofin to wa fun eto idajọ nipinlẹ Eko lo fun oun laṣẹ lati tilẹkun ile-ẹjọ lasiko yii, kawọn oṣiṣẹ kootu atawọn adajọ naa le gbadun isinmi Keresi ati ọdun tuntun pẹlu awọn mọlẹbi wọn.
O ni kawọn agbẹjọro atawọn mi-in tọrọ kan ma ṣe mu iwe ẹsun tuntun wa titi di igba tile-ẹjọ ba ṣilẹkun pada, afi ti ẹsun naa ba jẹ pajawiri to le nikan.