Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Lati ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ, lawọn ileewe ipinlẹ Ekiti yoo bẹrẹ si i wọle gẹgẹ bii aṣẹ tuntun ti Gomina Kayọde Fayẹmi pa lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ana.
Fayẹmi kede pe ọjọ Aje to n bọ lawọn akẹkọọ ipele agba keji (SS2), ipele girama kẹta (JS3) ati kilaasi kẹfa ileewe alakọọbẹrẹ (Pry 6) yoo wọle, nigba ti ipele agba kin-in-ni (SS1), ipele girama keji (JS2) pẹlu awọn onikilaasi kẹrin ati ikarun ileewe alakọọbẹrẹ (Pry 4 & 5) yoo wọle ni Mọnde to tẹle e.
Iwọle awọn onipele kin-in-ni girama (JS1) ati ileewe alakọọbẹrẹ kin-in-ni si ẹkẹta (Pry 1-3) di oṣu to n bọ, iyẹn ọjọ kẹwaa, oṣu naa, nigba tawọn ọmọ keekeeke yoo wọle lọjọ keji, oṣu kejila.
Fun awọn tileewe giga, lati ọjọ keji, oṣu to n bọ, ni wọn ti lanfaani lati wọle, ṣugbọn wọn gbọdọ ṣe awọn eto fun ilera oṣiṣẹ ati ọmọleewe.
Bakan naa ni Fayẹmi ni awọn ileejọsin le maa ṣe isin meji lopin ọsẹ, ṣugbọn ko ti i si anfaani fun iṣọ-oru tabi isin aarin ọsẹ. O ni awọn gbọngan ayẹyẹ le maa ba iṣẹ wọn lọ, ṣugbọn awọn to n ṣe ṣayẹyẹ ko gbọdọ ju aadọta eeyan.
Gomina naa waa kilọ fawọn araalu pe ofin lilo ibomu ati titakete sira ẹni ṣi wa digbi, awọn agbofinro yoo si tun maa mu awọn arufin.