Lẹyin oṣu mẹfa ti awọn ileewe ti di titi pa kaakiri orilẹ-ede yii lati fi dẹkun itankalẹ arun koronafairọọsi, ijọba apapọ ti kede pe ki gbogbo awọn ọmọleewe girama pada sẹnu ẹkọ wọn bayii.
Minisita feto ẹkọ, Adamu Adamu, lo sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja. O ni ijọba ti rọ gbogbo awọn oludari ileewe pata lati tẹle ilana to wa nilẹ lori bi opin yoo ṣe de ba itankalẹ arun ọhun, bi wọn ti ṣe n pada sẹnu iṣẹ.
Ọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni gbogbo awọn ọmọleewe kaakiri orilẹ-ede yii yoo pada sẹnu ẹkọ wọn lawọn ileewe ijọba.
Minisita Adamu ti sọ pe, awọn ileewe aladaani naa yoo kede igba to ba rọ wọn lọrun lati bẹrẹ ẹkọ, bẹẹ ni wọn gbọdọ ṣamulo gbogbo eto to wa nilẹ lati fi gbogun ti arun koronafairọọsi lawọn ileewe wọn.