Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun ta a wa yii, gẹgẹ bii ọjọ tawọn akẹkọọ yoo wọle pada sileewe wọn lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti wa nile nitori iwọde SARS.
Kọmisanna eto ẹkọ ati imọ sayẹnsi, Ọgbẹni Fẹmi Agagu, lo paṣẹ yii ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
O ni ijọba pinnu ati ṣi gbogbo ileewe alakọọbẹrẹ ati girama to wa kaakiri ipinlẹ Ondo pada niwọn igba ti alaafia ti n jọba lẹyin rogbodiyan to suyọ lasiko iwọde SARS ti wọn ṣe kọja.
Kọmisanna ọhun ni o di dandan fun gbogbo ileewe ijọba ati aladaani lati gbọran si aṣẹ tuntun naa, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ lọ.