Awọn janduku agbawere-mẹsin fibinu lu Usman pa, wọn lo sọrọ odi s’Anọbi  

Faith Adebọla

Ọkunrin ti wọn lọjọ-ori ẹ ko le ju ẹni ọdun marundinlogoji lọ, Usman Buda, ti kagbako iku ojiji, iku gbigbona si niku ọhun. Awọn janduku ti wọn ni agbawere-mẹsin ni wọn ni wọn lọọ fibinu ṣakọlu si i lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii. Ẹṣẹ ti wọn loloogbe naa da ni pe o sọrọ ta ko Anọbi Muhammadu, aṣaaju ẹsin Musulumi, wọn lọrọ odi kan lo sọ si i, ni wọn ba ṣedajọ ko-duro-gbẹjọ fun un, bi wọn ṣe ṣuru bo o ni wọn n fọgi mọ ọn lori, ti wọn si n lẹ ẹ loko, n ni wọn ba lu u pa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Sokoto, nibi ti iṣẹlẹ ibanujẹ yii ti waye, ASP Ahmad Rufai, lo fọrọ naa lede lori ikanni ayelujara rẹ, o ni iyalẹta ọjọ Aiku ọhun lawọn aladuugbo kan tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago idagiri, pe awọn agbawere-mẹsin kan ti ko ara wọn jọ o, wọn si ti bẹrẹ si i ṣakọlu si ẹni ẹlẹni, wọn si ti n ṣe e leṣe gidigidi, wọn ni iṣẹ alapata lọkunrin naa n ṣe.

O ni lọgan tawọn ti gbọ eyi ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Sokoto, CP Ali Hayatu Kaigama, Eria Kọmanda to n ri si awọn iṣẹlẹ oju popo, ati DPO Kwanni, ti ko awọn ọmọọṣẹ wọn kan sodi, ti wọn si tara ṣaṣa lọ sibi iṣẹlẹ ọhun.

Bawọn to n ṣakọlu naa ṣe gburoo fere yafun-yafun ọkọ ọlọpaa to n bọ lọọọkan, igbẹ laa fẹwe, oko la a wa nnkan ọbẹ lọrọ di, niṣe ni kaluku wọn sọ igi ati okuta ọwọ wọn silẹ, ni wọn ba fẹsẹ fẹ ẹ kawọn ọlọpaa too de ọdọ wọn, wọn si fi ẹni ti wọn n lu silẹ nibi toun ti n pọkaka iku.

 Wọn lawọn ọlọpaa ni wọn kọkọ gbe oloogbe Usman digbadigba lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun ti Fasiti Usman Danfodio, iyẹn Usman Danfodio Teaching Hospital, eyi to wa nigboro ilu Ṣokoto, awọn dokita si gbiyanju lati fun un ni itọju pajawiri, boya wọn yoo le doola ẹmi ẹ, amọ aṣọ o ba ọmọyẹ mọ, ọmọye ti rinhooho wọja, lẹnu itọju naa lo ti dakẹ, o ku patapata.

Alukoro Rufai ni awọn agbofinro ti fọn ka si igbogbo agbegbe tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ko ma lọọ di pe awọn eeyan kan maa fẹẹ gbẹsan iwa laabi yii, tori aforoyaro ki i jẹ koro tan, o lawọn ti pana eruku ija ati ibẹru to gbode ni gbogbo agbegbe naa, o si rọ kaluku lati maa lọ sẹnu iṣẹ ati okoowo rẹ wọọrọwọ.

O tun sọ pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ti n ba iwadii to lọọrin lo labẹnu, ati pe gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu akọlu to da ẹmi oloogbe yii legbodo ti wọn sa lọ ọhun, wọn sun ijiya wọn siwaju ni, gbogbo wọn lọwọ ofin ṣi maa to, ti wọn yoo si gbadajọ to tọ si wọn.

Leave a Reply