Jọkẹ Amọri
Iru ki waa leleyii ni ariwo to gba ẹnu awọn Onigbagbọ to wa ni Kafin-Koro, nijọba ibilẹ Paikoro, nipinlẹ Niger, nigba ti wọn gbọ pe awọn janduku kan wọle tọ Refurendi Isaac Achi, to jẹ Alufaa ijọ St.Peters and Paul Catholic Church, to wa niluu naa, ti wọn si dana sun un mọnu ile lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe gbogbo ọna ni awọn ẹni ibi naa san lati wọnu ile alufaa naa, ṣugbọn nigba ti eyi ko ṣee ṣe fun wọn nitori eto aabo to gbopọn to wa nibẹ ni wọn ba kuku binu sọna si inu ile ọhun, eyi lo si mu ki alufaa naa jona mọ inu ile yii.
Ọkan ninu awọn alufaa toun naa wa nitosi, to wa gbogbo ọna lati sa jade, Father Collins, ni ALAROYE gbọ pe wọn yin nibon lapa. Oju-ẹsẹ ni wọn sare gbe iranṣẹ Ọlọrun naa lọ sileewosan fun itọju to peye. Bẹẹ ni wọn wọ ajoku alufaa naa jade ninu ile ọhun.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Wasiu Abiọdun, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni, ‘‘Ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn janduku kan ti wọn di ihamọra nnkan ija ogun kọ lu ile Alufaa Isaac Achi, ni St. Peters and Paul Catholic Church, to wa ni oju ọna Daza, Kafin-Koro, nijọba ibilẹ Paikoro.
‘’Gbogbo ọna ni awọn janduku naa wa lati wọ inu ile ọhun, ṣugbọn nitori awọn eto aabo ti wọn ti ṣe sibẹ, wọn ko ni anfaani lati wọnu ile yii, eyi lo mu ki wọn dana sun ile naa, ti alufaa ọhun si jona mọle. Bakan naa ni wọn yinbọn mọ ọkan ninu awọn alufaa to tun wa nibẹ lejika, nigba ti o n gbiyanju lati sa lọ.
‘‘Awọn ọlọpaa lati Kafin-Koro ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn to ṣiṣẹ buruku naa ti lọ ki wọn too debẹ’’gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa naa ṣe wi.