Awọn janduku ya bo ile Tẹslim Fọlarin n’Ibadan, ọkada, ẹrọ ata, maṣinni iranṣọ, jẹneretọ ni wọn ko nibẹ

Kazeem Aderohunmu

O jọ pe pupọ ninu awọn araalu ni ko fẹẹ duro de ijọba tabi oloṣelu kankan mọ lori ohun iranwọ ti wọn maa n ṣe fun wọn, niṣe ni wọn lọọ n fọle, ti wọn si n fọwọ ara wọn ko ohun ti wọn ba fẹ.Idi ni pe awọn kan ti ya lọ sile ọkan ninu awọn sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Ibadan, Teslim Fọlarin. Gbogbo awọn ẹru bii ọkada, maṣinni atawọn nnkan mi-in ti ọkunrin oloṣelu naa ko pamọ tawọn kan gbagbọ pe o feẹ fi ṣe eto ironilagbara fawọn araalu ni wọn n ko kẹtikẹti bayii.

Ọkada bii igba, (200), firisa bii ọgọrun-un (100), ẹrọ ilọta bii igba (200) ati ẹrọ amunawa bii igba (200) ni awọn eeyan yii lọọ ko nile ọkunrin naa to wa ni Oluyọle, niluu Ibadan.

Ni kete ti wahala a n sun ile, a n sun teṣan ọlọpaa ti lọ silẹ lawọn eeyan orilẹ-ede yii tun ti jagbọn ohun mi-in, paapaa lawọn ilẹ Yoruba.

Nipinlẹ Eko gan-an ni wahala ọhun ti bẹrẹ, ile ounjẹ kan lawọn eeyan lọọ ja ni Mazamaza atawọn ibomi-in kaakiri Eko. Bẹẹ gẹgẹ nirufẹ iṣẹlẹ yii waye l’Ọṣun, Kwara atawọn ilu nla nla mi-in.

Ni bayii, ọna ara ti araalu tun gba yọ si awọn oloṣelu, paapaa awọn ti wọn ko ohun iranwọ rẹpẹtẹ sile, niṣe lawọn eeyan n lọọ ja ibi ti wọn ko wọn si, ti wọn si n fọwọ ara wọn ran awọn lọwọ.

Fidio kan lawọn eeyan tun n wo bayii, ilu Ibadan lo ti ṣẹlẹ, niṣe lawọn eeyan ya lọ si ile nla ti oloṣelu kan ko ọkada rẹpẹtẹ si, bi wọn ti ṣe n gbe e ni wọn n lọọ pera wọn wa, ti wọn si n ko o kẹtikẹti.

Ki i ṣe iyẹn nikan o, bẹẹ gẹgẹ lọrọ ri ni Ikirun, bi wọn ṣe n ko maṣinni ilọta, ni wọn n gbe ọkada ati ẹrọ amomitutu.  ALAROYE gbọ pe awọn oloṣelu kan lo ko o pamọ, ti wọn fẹẹ fi ṣeto iranwọ, ṣugbọn tawọn araalu lọọ n gbe e funra wọn bayii.

Ẹnikan to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ohun ti awọn eeyan naa n ṣe yoo lẹyin, nitori pupọ ninu awọn eeyan ti fidio gbe oju wọn yii, lo ṣee ṣe ki ọrọ ọhun di ẹjọ si lọrun nigba to ba ya.

 

Leave a Reply