Awọn meje yii ti ha ṣakolo sifu difẹnsi n’llọrin, eyi lohun ti wọn ṣe

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi meje kan wa bayii, ẹsun ole jija ni wọn fi kan wọn.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ naa ni Kwara, Ayọọla Michael Ṣhọla, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, lo ti sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi meji ti wọn jẹ janduku ti wọn ṣe kọ lu Arabinrin kan, Oluṣẹgun Taiwo, lagbegbe Sáńgò, niluu Ilọrin, ti wọn si gba baagi towo wa ninu rẹ ati foonu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii.

Ayọọla ni Oluṣẹgun Taiwo, lo mu ẹsun wa sileeṣẹ ajọ naa pe awọn janduku kan da oun lọna lasiko toun n lọ si agbegbe Post office, niluu Ilọrin, ti wọn si gba baagi, foonu atawọn dukia miiran lọwọ oun pẹlu tipa-tikuuku.

O ni lẹyin tawọn gunlẹ si agbegbe naa, nibi ti wọn ti n ṣe ifẹhonuhan eyi ti ko ba ofin mu lasiko tawọn oni kẹkẹ Maruwa n ṣe ifẹhonuhan lọwọ ni ọwọ tẹ awọn afurasi meje. Lẹyin iwadii lawọn ri i pe awọn afurasi meje ọhun lo maa n da omi alaafia ilu ru lagbegbe Sáńgò, to tumọ si pe awọn janduku ja ifẹhonuhan naa gba mọ awọn onikẹkẹ Maruwa lọwọ, ti wọn si fi n ja awọn araalu lole.

Ọga agba ajọ naa ni Kwara, Dokita Umar J.G. Mohammed, ti waa ni ki gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara, lọọ fọkanbalẹ pẹlu ajọ ṣifu difẹnsi aabo to peye wa fun araalu.

Ayọọla ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, awọn afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply