Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ọkunrin mẹta yii, Felix Sunday, Shomuye Musa ati Oluwatobi Michael, ti wa lẹka to n ri si ipaniyan nipinlẹ Ogun bayii, nitori iku ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Tunji George, ti wọn lu pa nitori wọn lo ji foonu olowo nla ti wọn n pe ni iPhone 6, lotẹẹli ti wọn n pe ni Keke, n’Iyana Iyẹsi, Ọta.
Ọjọruu, Wẹsdee, ti i ṣe ogunjọ, oṣu kẹwaa yii, lawọn ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, mu awọn mẹta yii, lẹyin ti aburo oloogbe torukọ tiẹ n jẹ Bọla George, lọọ ṣalaye fun wọn pe awọn eeyan naa fẹsun kan ẹgbọn oun pe o ji foonu olowo nla Iphone 6, wọn si so o mọlẹ pẹlu okun, bẹẹ ni wọn bẹrẹ si i lu u titi to fi ku mọ wọn lọwọ.
Awọn ọlọpaa de otẹẹli ọhun, wọn ri awọn to lu Tunji pa, wọn si mu wọn.
Nigba ti wọn n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ fawọn agbofinro, wọn lo da awọn loju gbangba pe oloogbe yii lo ji foonu naa, iyẹn lo jẹ kawọn maa lu u boya yoo jẹwọ, yoo si mu foonu naa silẹ fawọn, awọn ko mọ pe yoo ku sidii lilu naa ni.
Wọn tilẹ ti kọkọ sare n gbe e lọ sọsibitu nigba ti wọn fura pe lilu naa ti fẹẹ yiwọ, ṣugbọn wọn ko ti i de ọhun ti Tunji Geoge ti wọn n lu naa fi ku mọ wọn lọwọ.
Wọn ti gbe oku oloogbe lọ si mọṣuari Ọta fun ayẹwo, wọn ko awọn mẹta yii lọ sẹka to n ri si ipaniyan, nibi ti wọn yoo gba lọ si kootu lẹyin iwadii lẹkun-un rẹrẹ.