Awọn mi-in ko tori iṣẹ wa sidii tiata, iṣekuṣe ni wọn ba wa – Laide Bakare

Shakira Ọlaide Bakare, oṣere tiata Yoruba to gbafẹ, to gbajumọ, to si ti ile ọlọrọ jade wa ko nilo a n juwe lagbo tiata Yoruba lonii, idi ni pe ọpọ ere lo ti kopa ninu ẹ nilẹ yii ati loke okun. Ọmọ Ibadan lobinrin pupa reterete yii, inu oṣu kẹwaa yii naa lo pe ogoji ọdun laye.

Laide aya Orilowo ba ADEFUNKẸ ADEBIYI sọrọ nipa ara ẹ lẹyin ọjọọbi naa, bayii ni ifọrọwerọ naa ṣe lọ.

AKEDE AGBAYE: Ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) pere lẹ wa tẹ ẹ ti darapọ mọ awọn onitiata, ki lo wu yin to bẹẹ ninu iṣẹ naa?

LAIDE: Ootọ ni pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun pere ni mi nigba ti mo bẹrẹ iṣẹ tiata. Nnkan to wu mi ninu iṣẹ naa ni pe o maa n wu mi ki n maa gbe kamẹra. Ki n wa lẹyin kamẹra, ki n maa dari iṣẹ, ki n maa ya aworan. Oun lo fa a ti mo fi jẹ pe mo pada lọ si New York Film Academy lati kọ bi wọn ṣe n dari ere. Oun dẹ lo fa a to fi jẹ pe lẹnu ọjọ mẹta yii, mo ti fẹẹ mu didari ere (Directing) lọkun-un-kundun ju ti tẹlẹ lọ.

Ati pe baba mi ni irinṣẹ ti wọn fi n ya fiimu nigba yẹn, awọn onitiata ti wọn maa n waa lo otẹẹli baba mi dẹ maa n gba mi niyanju pe ki n darapọ, bi mo ṣe di ara wọn niyẹn.    

AKEDE AGBAYE: Ẹgbẹ oṣere wo lẹ waa darapọ mọ gan-an nigba naa?
LAIDE: 
 Mi o darapọ mọ ẹgbẹ kan pato, mo kan ṣaa maa n ri awọn onitiata ti wọn maa n waa lo ile wa to wa l’Ekoo ati kaakiri ibi ti baba mi nile si ni. Ṣugbọn ẹni ti mo kọkọ han ninu iṣẹ ẹ ni Muka Ray Eyiwumi. Ti mo ba gba ọlude wale lati ileewe ni mo maa n ba wọn kopa ninu iṣẹ ti wọn ba pe mi si.

AKEDE AGBAYE: Ṣe awọn obi yin ko dẹ binu pe ẹ n dara pọ mọ tiata nigba yẹn?

LAIDE: Awọn obi mi ti mọ awọn onifiimu kemi too mọ wọn, ọrẹ wa ni wọn jẹ, iyẹn o jẹ ki wọn binu rara. Paapaa, nigba to jẹ ko pa ileewe ti mo n lọ nigba naa lara, to jẹ inu ọlude ni mo n ba wọn ṣiṣẹ, ko si wahala. Mo ti pari ileewe girama tan ki n too bẹrẹ gidi.

AKEDE AGBAYE: O da bii pe ilu oyinbo lẹ n gbe ju, sibẹ wọn n pe yin si sinima nilẹ yii. Ọgbọn wo lẹ n da si i?

LAIDE: Mi o gbe ilu oyinbo mọ, igba kan ni mo lọọ gbebẹ fun bii ọdun meji aabọ. Awọn igba yẹn ni mo n ṣabiamọ lọwọ, mo lọọ bimọ sibẹ ni. Ti mo ba dẹ ti bimọ tan, ma a farabalẹ sibẹ lati tọju awọn ọmọ naa ki wọn le gbo daadaa ki n too bẹrẹ iṣẹ.  Ṣugbọn ni bayii, mo ti pada si Naijiria, ẹẹkọọkan ni mo maa n lọ siluu oyinbo nisinyii.

AKEDE AGBAYE: Bawo waa ni fiimu ṣiṣe niluu oyinbo ṣe yatọ si tibi? Ṣe wọn n fidi gba roolu (ipa) nibẹ naa bii ọdọ wa?

LAIDE: Haa, ko jọra wọn o, iyatọ to wa ninu iṣẹ tiata nilẹ yii ati ti oke okun pọ. Emi o ro pe wọn n fidi gba roolu o. Awọn to ba ni nnkan i ṣe pẹlu ara wọn maa ba ara wọn ṣe e nitori pe o wu wọn ni, ki i ṣe nitori ki wọn le fun wọn nipa kan ko ninu fiimu. Nitori agbekalẹ tiwọn yatọ, wọn ni ilana ti wọn n tẹle. Ẹni tẹ ẹ ba ri lori tẹlifiṣan nibẹ to n ṣe tiata, o kẹkọọ fun un gidi ni o, bi wọn ba ti kẹkọọ tan ni wọn n riṣẹ fi ṣe, iyẹn ko tiẹ le jẹ ki wọn ronu a n fidi gba roolu rara. Wọn dẹ tun n ri iranlọwọ gba lọdọ ijọba wọn daadaa, tiwa ko fi gbogbo ara ri bẹẹ.

Wọn n kawe daadaa, wọn dẹ maa n ṣe iṣẹ iwadii (Research) gan-an, wọn o da bii awa to jẹ pe ọrọ-aje ilu wa n da wa laamu, to n jẹ ka maa ya bara kiri lai ni afojusun kan.

Lọdọ wa naa dẹ ree, ti wọn ti n fidi gba roolu, ki i ṣe gbogbo igba naa lo n bọ si i, nitori o le fidi silẹ gan-an kiṣẹ ọhun ma bọ si i,  o kan fidi ṣofo lasan ni.

Awọn mi-in dẹ tun wa to jẹ wọn o ba ti iṣẹ wa, iṣekuṣe ni wọn ba de inu iṣẹ tiata tẹlẹ.

Ẹni to jẹ o ti nifẹẹ ọkunrin kan ninu iṣẹ yii tẹlẹ ko too darapọ mọ wọn, to ba jaja wọle, ohun to maa maa ba kiri naa niyẹn, ẹ o dẹ le da a lẹkun, nitori aye ta a wa yii ti di pe ki kaluku ṣe ohun to ba fẹ. Ṣugbọn eyi ki i ṣe nnkan ire, emi o fọwọ si i keeyan maa fidi gba roolu, ka fi ti ọmọluabi ṣe e lo daa.

AKEDE AGBAYE: Ọjọ keje, oṣu kẹwaa yii, le pe ogoji ọdun laye, njẹ nnkan kan wa tẹ ẹ ni lọkan lati maa ṣe pẹlu ọjọ ori yii ti ẹ o ki i ṣe tẹlẹ?

LAIDE: Wọn pọ, ohun ti mo fẹẹ maa ṣe pọ gan-an pẹlu ọjọ ori tuntun yii. Tẹlẹtẹlẹ, mo maa n bẹru pe ti mo ba dawọ le nnkan kan, mi o mọ iru ọmọ to maa bi. Ṣugbọn ni bayii, ọmọ to ba fẹẹ bi ni ko bi,awọn nnkan ti mo maa ṣe pọ, nitori teeyan ba n bẹru pe oun le ma ṣe aṣeyọri ninu nnkan, ko ni i gbiyanju rara, beeyan ko ba si gbiyanju nnkan wo, ko si kinni kan ti yoo ri ṣe ni daadaa.

AKEDE AGBAYE: Bobrisky, ọkunrin to n ṣe bii obinrin, wa sibi ọjọọbi yin, ẹ ba a dapaara pe o rẹwa ju ẹyin oninnkan gan-an lọ. Ṣe ọrẹ yin ni Bobrisky ni, ati pe ṣe ẹ fara mọ bo ṣe n mura bii obinrin?

LAIDE: Mo sọ bẹẹ o, mo ni o mura, o fain ju oninnkan lọ, pe ṣe ko dẹ waa si. Mo kan fi ba a ṣere ni.

Ṣe ẹ mọ pe ilana toun gba ni tiẹ niyẹn, o wo o pe oun laiki koun maa polowo awọn nnkan obinrin, nigba to ri i pe oun ri ara gbe e. O wo o pe toun ba n ṣe bẹẹ, ti wọn ba ri i lara oun, wọn maa laiki ẹ ni, o dẹ bẹrẹ si i ṣe e.

Emi o ki i bu ẹnu atẹ lu ohun tẹnikan ba n ṣe, mi o dẹ ki i sọ feeyan pe bakan ni ko ṣe lo igbesi aye ẹ, nitori eeyan kan naa ko le sọ fun mi pe bakan ni ki n ṣe lo igbesi aye mi.Nnkan ti kaluku fi n ṣe ohun to n ṣe, kaluku naa lo ye, ti a ba dẹ n wo o pe ẹsin ko fara mọ ohun to n ṣe, awa kọ ni Ọlọrun. Emi o dẹ mọ ibi teeyan kan ti n rin irin igbesi aye ẹ bọ, debii pe ma a waa sọ fun un pe bayii ni ko ṣe rin in.

Bi onigba ba ṣe pe igba ẹ ni mo n ba a pe e. To ba ji lọla to wọ ṣokoto ati ṣẹẹti, bi mo ṣe maa ba a gba a naa niyẹn. Gbogbo ohun yoowu ti mo ba ro, inu mi lo n gbe.

AKEDE AGBAYE: Gẹgẹ bii iya ọlọmọ mẹta ati iyawo lọọdẹ ọkọ, bawo niṣẹ yin yii ko ṣe ki i pa ile lara?

LAIDE: Ọlọrun naa ni, ẹni to ba dẹ wa laye yii to ba ṣi ni iya, oun gbogbo lo ni. Nitori iya ṣi le baayan mojuto ile ti wọn ba raaye nigba ti mo ba lọọ ṣe fiimu. Ọlọrun lo ṣe gbogbo ẹ fun mi, mo maa n ṣe Alhamdulilahi ni gbogbo igba.

AKEDE AGBAYE: Bi ọkọ atawọn ọmọ ba waa ni kẹ ẹ ma ṣe fiimu mọ, awọn fẹẹ maa ri yin nile deede, ki lẹ maa ṣe?

LAIDE:  Mi o ro pe wọn le sọ bẹẹ, wọn o le sọ ọ.

AKEDE AGBAYE: Awọn nnkan wo lẹ ti fi tiata ṣe bii aṣeyọri?

LAIDE: Ṣe nipa bi mo ṣe wọnu ile ati ilẹ tita ni, abi awọn nnkan ti mo tun ti ya si, iṣẹ tiata ni ipilẹ ẹ, nitori ẹ ni mi o ṣe le fi iṣẹ tiata ṣere. Mo dupẹ f’Ọlọrun lori tiata, ko sigba kan ti mo kabaamọ pe mo n ṣe tiata, o maa n dun mọ mi pe iṣẹ ti mo yan laayo ree.

AKEDE AGBAYE: Nigba tẹ ẹ fẹ Alaaji Orilowo(ATM), awọn eeyan sọ pe nitori owo lẹ ṣe fẹ wọn, ki lẹ le sọ nipa eyi?

LAIDE:  Ki i ṣe nitori owo o, loootọ awọn eeyan sọ bẹẹ, ṣugbọn ki i ṣe nitori owo

AKEDE AGBAYE: O da bii pe onifaaji ni Laide Bakare, bawo lẹ ṣe n ṣe faaji yin o?

LAIDE: Mi o tiẹ waa ki i ṣe faaji bẹẹ naa tẹlẹ o, ṣugbọn ni bayii, lara awọn nnkan ti mi o ki i ṣe tẹlẹ ti mo fẹẹ maa ṣe, faaji naa wa nibẹ.

AKEDE AGBAYE: Awọn ileewe wo lẹ lọ?

LAIDE: Mo lọ sileewe alakọọbẹrẹ ati girama niluu Eko, mo lọ si Yunifasiti Ibadan, mo kẹkọọ nipa iṣẹ tiata. Mo dẹ tun lọ si Yunifasiti Eko, mo kẹkọọ nipa itan (History and Strategic Studies) Mo lọ si New York Film Academy, mo kẹkọọ nipa fiimu ṣiṣe. Laipẹ lai jinna, mo maa bẹrẹ Masitaasi mi.

AKEDE AGBAYE: Ṣe ẹ ni awokọṣe ninu tiata, ki si ni amọran yin fawọn obinrin onitiata bii yin?

LAIDE: Mo ni role model (awokọṣe) rẹpẹtẹ, gbogbo ẹni to ba ti n ṣe daadaa nidii iṣẹ wa yii, inu mi maa n dun si wọn, mo dẹ maa n wo o pe emi naa laiki nnkan ti wọn n ṣe.

Amọran mi fawọn obinrin onitiata bii temi ni pe ki wọn ma gbojule ẹwa wọn, emi ni mo daa to yii, bẹẹyan ba gbojule iyẹn ti ko ba ni ọpọlọ, ko si bo ṣe le daa to, o maa yọ silẹ fun un.

Amọran mi fun wọn ni pe ki wọn tẹra mọṣẹ, ki wọn maa ṣe nnkan tuntun lọpọ igba, ko ma da bii pe gbogbo wa sun, a kọri sibi kan naa.

Leave a Reply