Awọn Musulumi Hausa ni ki Biṣọọbu Kukah kuro ni Sokoto

Ọrọ ti wọn pe lọ́wẹ́ ti n ni àárò ninu bayii pẹlu bi awọn ijọ Musulumi kan ṣe sọ fun Biṣọọbu Matthew Kukah ko fi ipinlẹ Sokoto silẹ patapata.

Ìjọ Muslim Solidarity Forum, lo sọ pe oun ko fẹẹ ri Kukah nipinlẹ náà mọ lori ẹsun pe o sọrọ ta kò ẹsin Islam àtàwọn Mùsùlùmí.
Ko ti ì ju bíi wakati mẹrinlelogun lọ ti Mattew Kukah náà pariwo sita pe nitori ọrọ ti oun sọ lọjọ Keresimesi lawọn ìjọ Mùsùlùmí kan, Jama’atul Nasril Islam, ti Sultan Sokoto n ṣolori ẹ
, ṣe kọjú ìjà sí oun, ti awọn eleyii naa tun sọ pe awọn fẹ ko fi ipinlẹ naa silẹ ti ko ba fẹẹ kan idin ninu iyọ.
Ọrọ ti Kukah sọ ninu ọrọ ìkíni fún ayẹyẹ ọdún 
Kérésìmesì ẹ fún aráàlú lo ti bu ẹnu atẹ lu ìjọba Buhari lori eto aabo ati ọrọ ajé tó ti dorikodo ni Naijiria.

Ojiṣẹ Ọlọrun yii tun sọ pe nie ni Buhari n fi ọrọ ṣegbe lẹyin awọn to ba jẹ tiẹ, paapaa awọn Hausa.
O ni ohun ti ijọba Buhari n ṣe, ka
 ni ki í ṣe pé o jẹ ọmọ Hausa ni, awọn ọja yóò ti fipa gbajọba yìí.
Latigba ti Biṣọọbu Matthew Kukah ti sọrọ yii ni awọn Hausa ti n ba a fa wahala
, ti wọn sọ pe ọrọ to sọ sí ijọba Buhari, ẹsin Islam ganan lo fi ba wí, atawọn ti wọn jẹ ẹlẹsin ọhun.
Bi ọrọ ọhun ṣe di wahala ni Kukah sọ pe lori ọrọ ifipa gbajọba
, kì í ṣe bi oun ṣe gbé é kalẹ niyẹn, ati pe ohun ti oun sọ ko ju bi a ti ṣe lè f’ọrọ ẹsin wá àlàáfíà àti iṣọkan sí aarin ilu.
O ni ọrọ ti ìjọ Jama’atul Nasril sọ pe leyin ti awọn Musulumi faaye gba oun tan nipinlẹ Sokoto, ni
e loun fẹẹ maa ge ọwọ tó fún oun lounjẹ nika jẹ.
O ni irufẹ ọrọ bayii, bíi ẹni fi ẹmi oun sinu ewu ni, bẹẹ lo le fa ikọlu latọdọ awọn ọmọ ijọ to n tẹle awọn eeyan yii kiri.
Ṣa o, Ọjọgbọn Isah Maishanu, ẹni tí 
ṣe adele alaga fún ìjọ Muslim Solidarity Forum, sọ pe Kukah korira ẹsin Islam, bẹẹ ni ko fara mọ ofin Sharia pẹlu.
Bakan naa lo tun fẹsun kan an pe pẹlu gbogbo anfààní to ti ri nilẹ Hausa laarin awọn Musulumi
, sibẹ, Kukah ko ri ohun to dara ri nipa ẹsin ọhun.
Ọjọgbọn Maishanu sọ pe fún ìdí èyí
, ojiṣẹ Ọlọrun náà gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ àwọn aṣáájú ẹsin Islam tabi ko fi ipinlẹ Sokoto silẹ jẹjẹ.
W
n láwọn ko le fara mọ bo ṣe fẹẹ fi ọrọ ẹnu ẹ da wahala silẹ laarin awọn Kristẹni atawọn Musulumi nipinlẹ náà.

Leave a Reply