Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Agbarijọpọ awọn Musulumi ilu Iniṣa, labẹ lnisa Muslim Elites, ti kilọ fun Gomina Ademọla Adeleke lati ma ṣe fi agbara yan ẹnikẹni le wọn lori gẹgẹ bii Imaamu Agba fun mọṣalaaṣi nla ilu naa.
Wọn ni bii ayọjuran ati ọna lati da omi alaafia ilu Iniṣa ru ni bi Adeleke ṣe na oẉọ ẹnikan to n jẹ Abdulakeem Jamiu, soke laipẹ yii gẹgẹ bii Imaamu Agba.
Bakan naa ni wọn kilọ fun Oluniṣa, Ọba Joseph Oyedele, lati takete si ọrọ to ni i ṣe pẹlu yiyan Imaamu Agba naa, nitori pe ẹni ti ko ba ni imọ ninu Islam ko le mọ ilana to tọ nipa yiyan aṣaaju fun mọṣalaaṣi apapọ.
Nibi ipade oniroyin kan to waye niluu Oṣogbo, ni awọn eeyan naa ti sọ pe ọrọ ọhun ti wa niwaju ile-ẹjọ giga ilu Ikirun, titapa si ofin si ni ki ẹnikẹni deede kede ẹnikan gẹgẹ bii Imaamu Agba.
Tẹ o ba gbagbe, lati ọdun mẹta sẹyin ti Imaamu agba mọṣalaaṣi nla naa tẹlẹ, Sheikh Surakat Aṣiyanbi, ti jade laye ni wahala naa ti bẹrẹ, mọṣalaaṣi pin si meji, abala mejeeji ni wọn si n sọ pe awọn yoo fa Imaamu agba kalẹ.
Amọ ṣa, Iniṣa Muslim Elites, ṣalaye pe ofin wa, bẹẹ ni ilana wa, eyi ti wọn maa n lo ninu ẹsin Islam lati yan Imaamu agba, awọn ko si ni i laju silẹ ki ẹnikẹni tapa si ilana ọhun.
Wọn ni yiyan Imaamu Agba gbọdọ tẹle akọsilẹ Kuraani, Hadith ati Sunnah, ko si gbọdọ ni ọwọ oṣelu ninu rara.
Wọn ni ijọba ipinlẹ Ọṣun ko gbọdọ huwa to le da ogun silẹ laarin awọn Ummah ati gbogbo awọn ọmọ ilu naa lapapọ lori ọrọ yiyan Imaamu agba yii.
Awọn eeyan ọhun ṣalaye pe ohun to lodi si iṣe mọṣalaaṣi naa ni bi Gomina Adeleke ṣe na ọwọ ẹnikan soke lai si ilana aatẹle, awọn ko si ni i gba ki ẹnikẹni ta ẹrẹ si aṣọ aala naa.