Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lẹyin bii osu kan tawọn dokita ti bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ nipinlẹ Ondo, awọn nọọsi naa ti fun ijọba ipinlẹ Ondo ni gbedeke ọjọ mẹta pere ki wọn too bẹrẹ iyansẹlodi tiwọn lori aabọ owo-osu ti Gomina Rotimi Akeredolu n san fawọn oṣiṣẹ.
Akọwe ẹgbẹ awọn nọọsi nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Aina Emmanuel Oluwasẹgun, lo sọrọ yii ninu lẹta kan to kọ si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
Oluwasẹgun paṣẹ fun gbogbo awọn nọọsi to n ṣiṣẹ ni gbogbo ileewosan ijọba lati bẹrẹ iyanṣẹlodi onikilọ ọlọjọ mẹta lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, si Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun ta a wa yii.
Yatọ si aabọ owo-osu to ni ijọba n san, eyi ti ko tẹ awọn lọrun, o ni awọn nnkan mi-in to jẹ ẹdun ọkan awọn ni bi ko ṣe si awọn nọọsi atawọn ohun eelo ti awọn fi n ṣiṣẹ to lawọn ileewosan ijọba to wa kaakiri ipinlẹ Ondo.