Awọn oṣiṣẹ eleto ilera fẹhonu han ni Kwara, wọn ni ijọba ko tọju awọn

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii, ni awọn nọọsi alabẹrẹ ati nọọsi agbẹbi ṣe ifẹhonu han niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, latari pe wọn nijọba ko tọju awọn to, ti wọn si n beere fun alekun owo ni kiakia.

Alaga ẹgbẹ awọn nọọsi alabẹrẹ ati nọọsi agbẹbi ni Kwara (National Association of Nigeria Nurses and Midwives (NANNM), Alaaji Aminu Shehu, to sọrọ nibi ifẹhonu han naa niluu Ilọrin,ni ijọba ko bikita nipa itọju awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni Kwara, ti wọn si ti pa wọn ti bii aṣọ to gbo. Fun idi eyi, kijọba mu alekun ba itọju awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni tibu-tooro ipinlẹ naa.

Aminu tẹsiwaju pe awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ lẹka eto ilera ni Kwara kere si iye awọn oṣiṣẹ to yẹ ko maa ṣiṣẹ, o ni lọwọ yii, awọn nọọsi alabẹrẹ ati agbẹbi ẹẹdẹgbẹrin (700), pere lo n ṣiṣẹ ni ileewosan ni Kwara, nọọsi ẹyọ kan lo n tọju alaisan ọgbọn, to si jẹ pe nọọsi marun-un lo yẹ ko maa tọju wọn. Fun idi eyi, ki ijọba gba nọọsi alabẹrẹ ati agbẹbi ẹgbẹrun mẹta kun awọn oṣiṣẹ to wa nilẹ, ki wọn si tun fi kun eto igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ naa, ki iṣẹ wọn le ja gaara.

O fi kun un pe lọdun to kọja ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera yii ja fun alekun owo iṣẹ wọn, ṣugbọn ijọba fi ida ọgọta si ogoje kun owo naa, ṣugbọn ko tẹ awọn lọrun tori pe ida ọgọrun-un ni awọn n beere fun un. Aminu ni bo tilẹ jẹ pe ijọba tun gba awọn nọọsi kan siṣẹ lọdun to kọja, awọn nọọsi naa kọwe fisẹ silẹ nigba ti wọn ri iṣẹ miiran to dara ju eyi ti wọn ṣe lọ.

 

Leave a Reply