Florence Babaṣọla
Awọn oṣiṣẹ eleto ilera (Health Workers) kaakiri ipinlẹ Ọṣun ti ṣeleri lati bẹrẹ ipolongo lori ewu to rọ mọ dida abẹ fun awọn ọmọbinrin (Female Genital Mutilation) ki aṣa naa le di ohun igbagbe patapata.
Lopin idanilẹkọọ ọlọjọ-mẹta ti ajọ Action Health Incorporated pẹlu ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin atawọn ọmọde nipinlẹ Ọṣun ṣe fun awọn oṣiṣẹ naa ni wọn ti ṣeleri pe aṣa ọhun gbọdọ di afisẹyin teegun n fiṣọ latari akoba nla to n ni lori awọn ọmọbinrin.
Lasiko eto naa, eyi to waye pẹlu ifọwọsowọpọ United Nations Population Fund (UNFPA), ni wọn ti jẹ kawọn eleto ilera mọ pe ọpọlọpọ wọn ni wọn ṣi n dọgbọn ṣatilẹyin fawọn obi ti wọn n dabẹ fun awọn ọmọbinrin labẹnu, eyi to buru pupọ nitori ọpọ iyalọmọ lo gbagbọ ninu ohunkohun tawọn oṣiṣẹ eleto ilera ba sọ fun wọn.
Ọga-agba nileeṣẹ eto ilera nipinlẹ Ọṣun, Dokita Gbenga Adepọju, ṣalaye pe loootọ ni aṣa naa ti dinku l’Ọṣun bayii, ṣugbọn bi ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ ki i tan leekanna.
Adepọju sọ pe ọpọlọpọ iyalọmọ ni ko mọ akoba nla ti dida abẹ n ṣe fawọn ọmọbinrin, gbogbo eeyan lo si gbọdọ dide lati gbogun ti iwa naa.
O sọ ọ di mimọ pe idanilẹkọ ọhun ṣe pataki nitori awọn oṣiṣẹ ilera gan-an ni wọn gbọdọ jẹ opomulero ninu igbesẹ lati gbogun ti aṣa naa. O ni bo tilẹ jẹ pe ko si iru iwa yii ni ọpọ ọsibitu mọ, sibẹ, ti awọn eleto ilera ba dari awọn iyalọmọ lọ sawọn ileewosan aladaani, wọn yoo gba si wọn lẹnu.
Aṣoju ajọ Action Health Incorporated, Arabinrin Nuriyat Abdulrasheed, ṣapejuwe dida abẹ fawọn ọmọbinrin gẹgẹ bii biba oju-ara ọmọ jẹ, iwa naa si jẹ titẹ ẹtọ ọmọniyan loju.
O ṣalaye pe laarin ọjọ kẹjọ si ogoji ọjọ ti wọn ba bi awọn ọmọbinrin ni wọn maa n dabẹ fun wọn, eyi to n ṣakoba fun ọjọ iwaju iru ọmọ bẹẹ, bo si tilẹ jẹ pe aṣa naa ti n dinku, o gbọdọ dopin patapata.
Nuriyat sọ siwaju pe awọn eleto ilera gbọdọ jẹ kawọn eeyan ẹsẹkuku mọ nipa awọn nnkan to le ṣẹlẹ nipasẹ dida abẹ fawọn ọmọbinrin, ki wọn si ṣamulo gbogbo ẹkọ ti wọn ti kọ nibi idanilẹkọọ naa.
Ọkan lara awọn nọọsi ọhun, Christiana Oloyede, sọ pe niwọn igba ti ẹsin Kristiẹni ati Islam ko ti fara mọ tabi pọn-ọn ni dandan lati da abẹ fun ọmọbinrin, gbogbo eeyan lo gbọdọ gbogun ti aṣa naa.
Lẹyin eto ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn yan lati ijọba ibilẹ Ọlọrunda ati Boripẹ ọhun ṣeleri pe awọn yoo jẹ aṣoju-rere lori igbogun ti abẹ dida fawọn ọmọbinrin.