Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ẹgbẹ ọdẹ ibilẹ, fijilante atawọn ọdọ ilu kan ti wọn da ara wọn loju l’Ajọwa-Akoko, n’ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, ni wọn ti fọn sinu igbo to wa lagbegbe naa lati ṣawari Olóṣó ti Oṣó-Àjọwá Akoko, Ọba Clement Ọmọọla Jimoh, tawọn agbebọn kan ji gbe lọ laafin rẹ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii.
ALAROYE ggbọ pe lẹsẹkẹsẹ ti iroyin ti jade pe wọn ti ji ori-ade naa gbe lawọn ọdẹ atawọn araalu kan ti ko ara wọn jọ, ti wọn si bẹrẹ si i wa gbogbo awọn aginjù to wa lagbegbe Akoko, titi de aala ipinlẹ Ondo ati Kogi, pẹlu erongba iati ṣawari ọba naa, ki wọn si gba a silẹ lọwọ awọn ajinigbe to ko o ni papa mọra.
Bakan naa lni ọga ọlọpaa patapata fun agbegbe Akoko, Murh Agboọla ati Paulinus Unah, to jẹ ọga fun wọn ní tesan Oke-Agbe, ti ṣabẹwo si aafin ti wọn ti ji ọba naa gbe, ti awọn mejeeji si fọkan awọn eeyan agbegbe ọhun balẹ pe igbesẹ ti n lọ labẹnu lori bi wọn yoo ṣe ri kabiyesi gba pada laaye laipẹ rara.
Ọrọ ijinigbe ọhun ni wọn lo ti ko jinnijinni ba awọn olugbe ilu Ajọwa ati agbegbe rẹ, ti ọpọ wọn si ti wọnu adura lọ lori iṣẹlẹ kayeefi naa.