Awọn ọdọ ṣewọde ifẹhonuhan l’Abuja, eyi lohun to n bi wọn ninu o

Adewale adeoye

Awọn ọdọ langba kan ti wọn n ṣewọde ifẹhonuhan l’Abuja, lati kilọ fawọn araalu to n doju ija kọ Igbakeji olori ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, Senetọ Barau Jibrin, pe o n ṣatilẹyin fun abadofin ti Aarẹ Tinubu gbe siwaju wọn. Wamu-wamu lẹsẹ wọn pe siwaju ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, ti kaluku wọn si gbe patako ti wọn kọ oniruuru ọrọ sinu rẹ dani. Bawọn kan ṣe kọ ọ pe, ‘Ko sohun to gbọdọ ṣe Senetọ Barau’, bẹẹ lawọn kan ni ‘Kin ni ẹṣẹ Barau’. Bi wọn ṣe n jo, bẹẹ ni wọn n kọrin oogun pe awọn ko ni i gba fawọn ọta Senetọ Barau to n halẹ mọ ọn.

ALAROYE gbọ pe ohun to mu ki awọn ọdọ naa jade sita lati waa ṣewọde ifẹhonuhan naa ni pe wọn gbọ pe awọn kan n ba Senetọ Barau ja nileegbimọ yii nitori ti wọn fẹsun kan an pe o n ṣatilẹyin fun abadofin ti Aarẹ Tinubu gbe siwaju awọn aṣofin agba yii.

Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja lọ yii ni Sẹnetọ Barau jokoo lori aga aṣẹ, iyẹn lasiko ti Olori ile naa, Sẹnetọ Goodswill Akpabio, ko si nile. Lasiko ijiroro ọhun ni wọn ti sọrọ nipa abadofin ti Aarẹ Tinubu fi ranṣẹ si wọn. Ọrọ abadofin ọhun daja nla silẹ lọjọ naa, tawọn Sẹnetọ kan, paapaa ju lọ, lati Oke-Ọya lọhun-un ta ko aba naa ati ọna ti wọn fẹẹ gba gbe e wọle.

Lara awọn aṣofin to bẹnu atẹ lu ijiroro lori abadofin ọhun ni Sẹnetọ Ali Ndume, lati ipinlẹ Borno, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC atawọn mi-in.

Ọrọ naa bi awọn kan ninu debii pe wọn fẹẹ kuro nileegbimọ lọjọ naa, ṣugbọn wọn tun pe ara wọn sakiyesi, ti wọn si pada jokoo lati maa ba iṣẹ ilu ti wọn yan wọn fun lọ.

Titi di asiko yii, Senetọ Barau ko ti i sọ tẹni to n ṣe lori ọrọ abadofin naa, ṣugbọn awọn kan n fẹsun kan an pe o maa fara mọ abadofin naa nigbẹyin ni. Eyi lo n bi awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan ninu, ti awọn ẹya Hausa mi-in naa si n sọrọ ti ko daa si i. Nitori rẹ lawọn ọdọ yii fi ya wọ ileegbimọ naa lati ṣatilẹyin fun un pe ko si ohun to buru ninu ohun ti aṣofin to n ṣoju wọn lati ipinlẹ Kano naa ṣe.

Wọn ti ka abadofin ọhun seti awọn aṣofin, wọn si ti fi i ṣọwọ si alaga igbimọ alabẹ ṣekele kan to n ri sọrọ owo nina nileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, eyi ti Sẹneto Sani Musa, lati ẹkun Niger-East jẹ alaga rẹ pe ki wọn ṣiṣẹ le e lori, ki wọn si pada waa jabọ fawọn laipẹ.

Olori ileegbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Goodswill Akpabio naa tun gba igbimọ naa niyanju pe ki wọn gba amọran lọdọ awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ-aje bii ‘National Economic Council’ (NEC), ẹgbẹ awọn gomina, ‘Nigerian Governor Forum’ (NGF) atawọn ẹka ijọba mi-in to lohun un ṣe pẹlu ọrọ abadofin ọhun, ki wọn si waa jabọ fawọn.

 

Leave a Reply