Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi nnkan ko ṣe fara rọ lorileede yii, tawon araalu ko rowo gba ni banki lati ra ohun ti wọn fẹ ati lati ṣe ohun gbogbo ti wọn fẹẹ ṣe, ti epo bẹntiroolu naa ko si ṣee kọ lu, eyi to mu ki owo ọkọ atawọn ohun to n lo epo bẹntiroolu gbowo lori, awọn ọdọ kan ti kora wọn jade niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si n fẹhonu han lori inira buruku ti aisi owo Naira ati epo bẹntiroolu n mu ba wọn.
Adugbo Iwo Road, niluu Ibadan, ni awọn ọdọ yii kora wọn kọ si, ti wọn si di oju ọna ti gbogbo awọn arinrin-ajo maa n gba naa pa.
Eyi ti mu inira ba awọn arainrin-ajo to n gba awọn agbegbe naa kọja. Oju ọna yii ni awọn to n lọ si ilu Ọyọ, Ogbomọsọ, Ilọrin atawọn ilu lapa Oke-Ọya yoo gba kọja, Bakan naa ni gbogbo awọn arinrin-ajo to n lọ si awọn ipinlẹ bii Ọṣun, Ondo, Ekiti atawọn apa Oke-Ọya, to fi mọ awọn ilẹ Ibo kan yoo ba oju ọna yii kọja. Ṣugbọn niṣe ni gbogbo ọkọ duro, nitori ko si bi wọn ṣe le kọja pẹlu bi wọn ṣe di ọna naa pa.
Lati Iwo Road yii la gbọ pe awọn to n fẹhonu han naa ti kọja lọ si Sekiteriati ijọba, nipinlẹ Ọyọ, igi, kumọ, okuta atawọn nnkan bẹẹ ni wọn ko dani, ti ti wọn si n sọko si gilaasi awọn ọfiisi to wa nibẹ, nibi ti wọn ti ba ọpọ nnkan jẹ lawọn ọfiisi ọhun.
ALAROYE gbọ pe wọn ṣe ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ ọfiisi gomina leṣe, bẹẹ ni apa awọn agbofinro ko ka awọn ọdọ naa, eyi to mu ki wọn ti geeti to wọ inu ileesẹ ijọba naa pa.
Oriṣiiriṣii akọle ni awọn ọdọ naa gbe dani, ti wọn si n kọrin lọlọkan-o-jọkan. Lara ohun ti wọn kọ sara akọle naa ni: ‘Buhari, iya yii pọ’, ‘ko sowo, ko si epo, ṣe ẹ fẹẹ pa wa ni’ ijọba Buhari, wa nnkan ṣe sọrọ to wa nilẹ yii’’ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni wọn n gbe kiri.
Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii kan naa ni awọn ọdọ kan ti wọn pera wọn ni Yoruba Youth Council ti kọkọ pariwo sita pe bi nnkan ṣe n lọ lorileede yii pẹlu bi ko ṣe si owo, ti ko si tun si epo, ti ohun gbogbo si wọn gogo ti kọja afarada.
Wọn ni iya ọna meji lo n jẹ wa ni Naijiria bayii. Ba a ṣe n jiya epo la n jiya owo Naira ti wọn paarọ ti awọn araalu ko ri gba, eyi to mu ki ọrọ aje dẹnukọlẹ.
Bii ọjọ marun-un sẹyin, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn ọdọ kan naa ti wọn pera wọn ni Nigerian Youth Congress for Peace and Development (YCPD), kora wọn jọ niluu Jos, nipinlẹ Plateau, ti wọn fẹhonu han lori bi wọn ko ṣe ri owo tuntun tijọba paarọ gba, ti epo si tun wọn gogo, eyi to mu nnkan nira faraalu. Wọn ni bi nnkan ba n lọ bayii, eto idibo kankan ko ni i waye lorileede yii.