Awọn ọdọ kan ṣewọde ta ko ile-ẹjọ to ga ju lọ lori gbedeke pipaarọ owo Naira

Monisọla Saka

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun yii, lawọn ọdọ kan ya bo titi ilu Abuja, ti i ṣe olu ilu orilẹ-ede yii, pẹlu ibinu, lati le fẹhonu han ta ko idajọ ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorilẹ-ede da lori owo Naira. Gẹgẹ bi idajọ kootu to ga ju lọ ọhun, wọn ti wọgi le aba ijọba apapọ ati ti olori banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, lori erongba wọn lati fopin si nina owo Naira atijọ, bẹrẹ lati ọjọ Ẹti Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2023 yii.

Gẹgẹ bi ikede banki apapọ tẹlẹ, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lọjọ ti wọn fawọn araalu da lati na owo atijọ yii, ṣugbọn wọn tun sun un siwaju di ọjọ kẹwaa, oṣu Keji yii. Ọkan lara idi ti banki apapọ ilẹ yii fi n gbe ofin ọlọkan-o-jọkan jade lori owo Naira tuntun ati ti atijọ yii ni lati le bẹgi dina ibo rira ati magomago lasiko ibo aarẹ ti yoo waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji yii, ati ibo awọn gomina to maa waye lọjọ Kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Awọn olufẹhonu-han ọhun, ti wọn kora wọn jọ siwaju olu ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa, ati iwaju ọọfiisi adajọ agba ilẹ Naijiria, rọ banki apapọ lati ma ṣe yi ipinnu wọn pada nitori idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ. Nigba ti ọrọ owo gbigba yii ti da oriṣiiriṣii wahala silẹ, tawọn eeyan si n fi owo ra owo wọn jade latinu banki, awọn ọdọ yii ro pe sisun ọjọ ti owo Naira atijọ yoo kasẹ nilẹ siwaju ko yatọ si pe wọn tubọ n sun iya to n jẹ awọn araalu siwaju si i ni.

Oriṣiiriṣii patako ti wọn kọ awọn ọrọ to n dun wọn lọkan, ti wọn si n fẹ atunṣe lori ẹ ni wọn gbe lọwọ. Ọkan lara ọrọ ti wọn kọ ni pe, ‘Onidaajọ Ariwoọla, jawọ ninu lilo ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ yii lati tẹ ijọba alagbada loju mọlẹ’. Bẹẹ lawọn eeyan yii tun naka aleebu si adajọ agba ilẹ yii, Olukayọde Ariwoọla, lori bo ṣe n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ naa, Bọla Ahmed Tinubu, titi kan awọn gomina maraarun ti wọn n binu si ẹgbẹ wọn lẹgbẹ oṣelu PDP. Wọn ni o mọ-ọn-mọ da ẹjọ naa lati ṣegbe fawọn eeyan ẹ yii ni.

Leave a Reply