Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe orileede Naijiria ti ba ijakulẹ pade lori ijọba tiwa-n-tiwa ti a n ṣe, nitori naa, asiko ti to lati pada si asiko ti agbara wa lọwọ awọn ọba lati ṣakoso agbegbe wọn.
Lasiko ti Ọba Akanbi n gbalejo Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Moshood Lekan Balogun, lalejo laafin rẹ niluu Iwo, lo ṣalaye pe irufẹ iṣejọba ti orileede yii n lo bayii ki i ṣe dẹmokresi.
O ni awọn oloṣelu orileede Naijiria ti mu ijakulẹ ba awọn araalu ninu iwa ati iṣe wọn nipasẹ oniruuru awọn iwa aitọ ati igbesẹ ifiyajẹni ti wọn n hu, idi si niyẹn ti inu awọn araalu yoo fi dun ti agbara ba pada sọdọ awọn ọba.
Oluwoo fi kun ọrọ rẹ pe afihan iwa were (demonstration of crazy) ni ohun ti a n pe ni dẹmokresi bayii, idi si niyẹn ti ko fi si aṣeyọri nidii rẹ nitori ki i ṣe nnkan to mọ wa lara.
O ni, “Ṣe lawọn oloṣelu asiko yii n fi ara ni awọn araalu, ọba to ba si fẹran ilu rẹ ko ni i fi aye ni wọn lara. Tiṣejọba ba pada sọdọ awọn ọba, iru eyi ti awọn oyinbo ti wọn mu wa sin gan-an, iyẹn Biritiko, n lo, nnkan yoo yatọ.
“Awọn araalu yoo lagbara lati le ọba to ba huwa ti wọn ko fẹ kuro lori ipo. Awọn araalu ni wọn yoo maa ja fun awọn ọba ti wọn ba ṣe daadaa, nipasẹ bẹẹ, aṣẹ ati agbara yoo pada sọwọ awọn ọba”.
Ọba Akanbi, ẹni to ni inu oun dun pupọ fun abẹwo Olubadan naa sọ pe abẹwo naa jẹ manigbagbe nitori pe yoo tubọ mu ki ibaṣepọ to dan mọnran wa laarin ilu Iwo ati Ibadan.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọba Balogun gboriyin fun Oluwoo fun bo ṣe n fi gbogbo igba wa itẹsiwaju awọn araalu naa, ati bi ko ṣe kaaarẹ lori awọn nnkan ti yoo mu idagbasoke ba ilu Iwo.