Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni awọn ọlọdẹ mẹta kan wa bayii ti wọn ti n wi tẹnu wọn lori ọrọ iku awakọ kan, Adewale Olowolafẹ, ẹni ti wọn lu pa loju ọna Ìjàrẹ́, niluu Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.
Awọn afurasi mẹtẹẹta ti wọn jẹ ọlọdẹ, ti wọn si gba lati maa ṣọ agbegbe naa la gbọ pe wọn da ọwọ jọ lu Adewale lori ede aiyede to bẹ silẹ laarin wọn, ṣe ni wọn si lu ọmọkunrin ọhun pẹlu irin ati apola igi titi to fi ku mọ wọn lọwọ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun lasiko to waye pe ilu Ijarẹ, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, ni Adewale ti wa, to si yan iṣẹ awakọ laayo gẹgẹ bii iṣẹ oojọ rẹ.
O ni ko sẹni to mọ ohun to da oun ati obinrin kan pọ ti iyẹn fi lọọ fẹjọ rẹ sun awọn afurasi naa, ṣugbọn eyi ti wọn iba fi yanju aawọn to wa laarin awakọ naa ati obinrin yii, niṣe ni wọn ki awakọ yii mọlẹ, ti wọn si dana iya fun un, eyi to pada ṣokunfa iku airotẹlẹ to mu ẹmi dẹrẹba naa lọ.
Ni bi tọrọ naa buru de, o ni ṣe lọpọ awọn to n ṣe agbado ta lagbegbe naa tun n fa igi idana wọn yọ, ti wọn si n ko o fun awọn ọlọdẹ naa lati maa fi na oloogbe yii.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori rẹ. O ni loootọ lawọn ti fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi mẹtẹẹta ti wọn fẹsun kan pe awọn ni wọn na ọkunrin naa titi ẹmi fi bọ lara rẹ.
Awọn afurasi ọhun lo ni awọn ti fi ṣọwọ sọdọ awọn ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaran.