Faith Adebọla
Awọn ọmoogun kan, eyi ti Jagun-jagun Ibrahim Traore lewaju fun, ti le Ọgagun Paul-Henri Sandaogo Damiba, kuro lori aleefa gẹgẹ bii olori ijọba orileede Bukina-Fasso, Traore si ti di olori ijọba ologun tuntun lorileede naa.
Traore atawọn ọmoogun mẹrinla kan ti wọn fara han lori tẹlifiṣan ni wọn kede iṣẹlẹ yii ninu ọrọ ti wọn bawọn araalu sọ lori redio ati tẹlifiṣan, niluu Oagadougou, ti i ṣe olu-ilu ilẹ wọn, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022.
Captain Traore ni idi tawọn fi ja ijọba naa gba ko ṣẹyin eto aabo to dojuru lorileede naa, o lawọn ti ṣakiyesi pe apa Damiba ko ka a, tawọn o ba si tete gbegbesẹ tawọn gbe ọhun, nnkan aa buru kọja aala.
Bakan naa lo tun kede pe awọn ti so iwe ofin orileede naa rọ na, titi kan eto idajọba pada fawọn oloṣelu, awọn si ti tu ijọba Ọgagun Damiba ka. O lawọn ti ti gbogbo ilẹkun ẹnubode to wọ orileede naa, awọn si ti fofin de igbokegbodo oṣelu ati iṣelu titi dọjọ mi-in ọjọọre. Bẹẹ ni wọn tun kede ofin konile-gbele laarin aago mẹsan-an alẹ si aago marun-un owurọ.
Eyi ni igba keji laarin oṣu mẹjọ ti wọn maa paarọ ijọba lorileede Burkina-Faso. Ọgagun Damiba lo gbajọba lọwọ Aarẹ Rock Kabore, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Ki-in-ni, ọdun yii, o le baba agbalagba ẹni ọdun marundinlaaadọrin naa lugbẹ, o si fopin si iṣejọba demokiresi orileede naa. Ṣe paṣan ta a fi na iyaale nbẹ loke aja fun’yawo, awọn ṣọja ẹlẹgbẹ rẹ lo yẹ aga nidii oun naa.
Damiba ṣeleri bo ṣe gbajọba tan ni January pe oun yoo wa iyanju si eto aabo to mẹhẹ, oun yoo si da ijọba pada fawọn oloṣelu laarin ọdun meji, ṣugbọn ko ju oṣu mẹta pere lọ lẹyin eyi ti ina ija fi n ran kaakiri orileede naa, latari awọn agbebọn ati awọn ọmoogun tinu n bi, ti wọn n ṣe akọlu saraalu, ti wọn si n fẹmi ṣofo.
Ko ti i sẹni to mọ ipo ti Damiba wa bayii lẹyin ti wọn mu un laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee ọhun, alaye kan ti wọn ṣe laṣaalẹ ọjọ naa sọ pe eto ti n lọ lati pana aawọ ati ibinu awọn jagunjagun ti wọn gbomi ọtẹ kana nileeṣẹ oloogun ilẹ Burkina-Faso, gẹgẹ bi Alukoro wọn, Nionel Bilgo, ṣe sọ.
Ẹ oo ranti pe ọkan lara awọn orileede Iwọ-Oorun Africa ni Burkina-Faso, lẹgbẹ orileede Nijee (Niger), to jẹ alamulẹgbẹẹ Naijiria.