Awọn ọlọja  fariga fun ọmọ Tinubu, wọn ni aaye ohun to ṣe l’Ekoo ko si l’Edo

Adewale Adeoye

Orin, ‘ohun to o le gba, ma fi lọ ẹda ẹgbẹ rẹ’ ni agbarijọpọ awọn ọlọja kan nipinlẹ Edo bẹrẹ si i kọ fun Iyaafin Fọlashade Ojo Tinubu, ọmọ Aarẹ ilẹ wa ti i ṣe Iyalọja ipinlẹ Eko lọwọ bayii.

Niṣe ni awọn obinrin naa ko ara wọn jọ lẹ́gbẹ̀lẹ́gbẹ̀, bawọn kan ṣẹ n kọrin lawọn kan n lu agogo, tawọn mi-in si ja ewe lọwọ. Ko s’ohun meji tawọn ara inu ọja naa fi jawe lọwọ, ti wọn si n ṣewọde ifẹhonu han nita gbangba ju ti ẹsun ti wọn fi kan an lọ. Wọn ni o fẹẹ ti ilu Eko waa yan ayanfẹ rẹ kan le awọn lori gẹgẹ bii iyalọja ninu ọja igbalode kan tawọn ti n ṣiṣẹ aje awọn bayii.

ALAROYE gbọ pe, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, ni awọn ọlọja naa tinu n bi gidi lori ohun ti wọn ka kun iwọsi ọhun ṣewọde ita gbangba naa laarin ọja wọn, ti wọn si fi aifunnu wọn han sawọn oniroyin nipa iwa aikaayan-kun ati afojudi ti wọn ni Fọlashade Ojo Tinubu hu sawọn ninu ọja naa bayii.

Wọn ni niwọn igba to ti jẹ pe awọn kọ lawọn n ba a dari ọja rẹ niluu Eko, ilu Eko naa ni ko fi idari rẹ mọ, ko ma waa da si ohun to n lọ ninu ọja awọn nipinlẹ Edo, debii pe yoo waa gbiyanju pe oun fẹẹ yan Iyalọja fun awọn.

Ọkan ninu awọn obinrin ọlọja to ṣaaju awọn oluwọde naa to sọrọ sọ pe, ‘Mo mọ Fọlaṣade daadaa, a jọ maa n pade nibi ipade awọn adari ọlọja. Ko si si igba kankan ti ẹnikẹni da si ohun to n ṣe l’Ekoo, niwọn igba ti a ko ti da si ohun to n ṣe, ko yẹ ki oun naa wo ọdọ wa rara. Ẹ ba wa kilọ fun un ko ma da wahala silẹ laarin ọlọja nipinlẹ Edo o’.Bẹẹ ni obinrin naa sọ.

Leave a Reply