Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bo tilẹ jẹ pe Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe o ṣee ṣe koun fofin de awọn ọlọkada nipinlẹ Ogun nitori ai tẹle ofin Korona, ṣugbọn nigba ti iṣẹ ọhun ba pe awọn ọlọkada ni awọn naa le ṣiṣẹ, awọn alalupupu funra wọn n binu lọwọ yii, wọn ni awọn ẹgbẹ loriṣiiriṣii (Union) ko jẹ kawọn jere iṣẹ awọn.
Ọjọbọ to kọja yii ni akojọpọ awọn ọlọkada gba ọfiisi ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta lọ, l’Ake, a si gbọ pe awọn mi-in lọ s’Oke-Mosan, nileeṣẹ ijọba. Ohun ti wọn n sọ ni pe ẹgbẹ mẹta lawọn n ṣiṣẹ sin, awọn mẹtẹẹta lo n ja tikẹẹti fawọn, bẹẹ ni wọn n ta sitika(sticker) tawọn ko gbọdọ ma ra.
Ẹgbẹrun meji aabọ ni wọn pe sitika, nigba ti tikẹẹti ojoojumọ jẹ ẹẹdẹgbẹta Naira. Bẹẹ, ẹni ti ko ja tikẹẹti yii ko ni i le ṣiṣẹ, nitori wọn yoo mu un ni. Wọn tun ni owo kan naa wa to n lọ sapo ijọba, bẹẹ, ọwọ awọn naa ni wọn ti n gba a lojumọ.
Gbogbo eyi ko jẹ ki iṣẹ naa pe mọ gẹgẹ bi Ọgbẹni Samuel Ọdẹyẹmi to gbẹnu sọ fawọn yooku ẹ ṣe wi, nitori ọpọ awọn lo jẹ pe awọn ko ti i sanwo ọkada tawọn fi n ṣiṣẹ tan, awọn ṣi n sanwo naa diẹdiẹ ni, awọn si gbọdọ gbọ bukaata nile, kawọn naa yọ nita gẹgẹ bii ẹni to niṣẹ to n ṣe.
Awọn ẹgbẹ mẹta to wa fawọn ọlọkada nipinlẹ Ogun ni: ACOMORAN, AMORAN ati ROMO, awọn naa lawọn ọlọkada tori ẹ mẹjọ lọ si ọfiisi ijọba ibilẹ naa.
Gbogbo igbiyanju wa lati ba awọn ṣiamaanu ẹgbẹ yii tabi awọn amugbalẹgbẹẹ wọn sọrọ ko bọ si i rara, nitori ohun ti gomina sọ lọjọ keji iwọde awọn to fẹhonu han naa ni wọn dojukọ. Bi ijọba ko ṣe ni i mu ileri rẹ ṣẹ nipa kiko ọkada kuro nilẹ lo ṣi wa ninu awọn atẹjade to n ti ọdọ wọn wa.
Olori Amoran jakejado Naijiria, Alaaji Samsondeen Apẹlogun, ti a ri ba sọrọ laaarọ ọjọ Satide sọ pe oun ko le sọ si ọrọ naa, nitori oun ki i ṣe aarẹ ipinlẹ Ogun, ti gbogbo Naijiria loun.