Awọn ololufẹ Pasuma n binu si Taye Currency, wọn ni ko gbọdọ wa s’Ekoo o

Ọrẹoluwa Adedeji

Ọkunrin olorin ilu Ibadan to gbajumọ daadaa nni, Taye Adebisi Akande, ti gbogbo eeyan mọ si Taye Currency, ti ṣalaye bi ọrọ to sọ lode ere kan to da wahala silẹ, to si bi awọn ọmọlẹyin Wasiu Alabi Pasuma ati Sẹfiu Alao Baba Oko ninu o.

Laipẹ yii ni ọkunrin naa kọrin lagbo ere kan, nibi to ti sọ pe Obesere ni Pasuma n kọpi nigba to kọkọ bẹrẹ orin, to si sọ pe Shina Akanni ni Sẹfiu Alao kọpi ni tiẹ. Ọrọ to sọ yii ko dun mọ awọn ololufẹ Paso ati Sẹfiu ninu, wọn ni bawo lo ṣe maa sọ iru nnkan bẹẹ jade ni gbangba, ati pe ohun ti ko mọ lo n sọrọ le lori. Wọn ni ọjọ wo ni wọn bẹrẹ si i gburoo tiẹ paapaa nidii orin.

Ibinu ọrọ yii ni manija Sẹfiu Alao, Saheed Ojubanirẹ,  fi sọrọ lorukọ ọga rẹ, ti wọn si ni promota kan to wa l’Agege lo n sọ awọn ọrọ ti ọmọkunrin naa ko mọ fun un.

Ọrọ ti Currency sọ yii ti n bi awọn ololufẹ Pasuma ninu o, ti wọn si n leri si i pe Ibadan rẹ naa ni ko jokoo si o, awọn ko gbọdọ ri i l’Ekoo. Wọn ni iru itukutu wo lo n tu yẹn, pe bi eeyan kan ba tiẹ maa sọrọ, ki i ṣe Currency lo yẹ ko wa nidii ibajẹ Pasuma. Ati pe ohun ti ko mọ lo n sọ.

Eyi lo mu ki Taye Currency naa jade bayii o, to si ti forin ṣalaye ọrọ pe awọn kan ni wọn ṣi oun gbọ, awọn eeyan naa lo si fẹẹ da wahala silẹ laarin oun ati ọga oun, iyẹn Alabi Pasuma.

Currency ni, ‘’Emi pẹlu ọga mi Pasuma a jọra. Wọn ni mo sọrọ kan lori ayelujara pe ko daa, mo dẹ gba, ṣugbọn ẹyin tẹ ẹ maa n ṣiiyan gbọ, ẹ o le da aarin wa ru o, emi ati Pasuma Baba Wasila. Bẹ ẹ ba ti n gbiyanju ẹ tipẹtipẹ, ẹ lọ gbẹnu lọwọ, ẹni to ba da si ọrọ wa, ori ẹ la maa fi fọ ọ. Ba a ṣe n ṣe lati 1992 titi to fi di asiko yii niyẹn. O ti to ọgbọn ọdun ta a ti jọ wa. Ẹ o le da aarin wa ru, ẹni to pọn Paso le to Taye, mi o ti i ri i. Ẹni to gbe e fun Paso to Currency, mi o ti i ri.

‘’Ti n ba sọ ọkan tẹ ẹ ba binu, o ku sọwọ yin, ṣugbọn o ti ye ọga mi Paso ọga mi, ọga mi ga-an ni Paso….

Nigba to n sọrọ nipa ẹsun ti Sẹfiu Adekunle, fi kan an, alaye to sẹ ni pe awọn kan naa ni wọn fẹẹ da wahala silẹ laarin oun ati Ṣẹfiu Alao Baba Oko.

O ni, ‘’Ẹni ti mo maa n pọn le ni Sẹfiu, oun naa si maa n pọn mi le, gan-an, ẹ tun fẹ maa da ija silẹ laarin wa. Ẹ lọọ sọra’’. Bayii ni Taye forin ṣalaye bi ọrọ naa ṣẹ jẹ pe awọn kan ni wọn ṣi oun gbọ.

Ṣugbọn awọn ọmọlẹyin Pasuma ti fun un lesi, wọn ni nitori pe Paso jẹ eeyan jẹẹjẹẹ ti ko si ka nnkan si lo ṣe fẹẹ maa gun un garagara, wọn ni afi ko ṣọra pẹlu igberaga ẹ.

Bakan naa ni ẹlomi-in tun sọ pe ‘Ọgbẹni, iwọ naa ṣe aṣiṣe, ko yẹ ko o sọ iru ọrọ bẹẹ jade rara, nitori Pasuma ko kọpi ohun ẹnikẹni. Ẹlomi-in tun ni, to o ba to bẹẹ ko o wa si Eko, a maa fun ẹ ni wotowoto.

Bo tilẹ jẹ pe Currency ti tọrọ aforiji lọdọ Paso, sibẹ, ko jọ pe inu awọn ololufẹ rẹ ko ti i walẹ lori abuku ti wọn lo fi kan ọga onifuji naa.

 

Leave a Reply