Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Adabọnyin Ẹkun, Ọba Adetokunbọ Gbadegẹṣin Tẹjuoṣo, Olu Orile Kemta, l’Abẹokuta, to sọrọ soke lasiko ti ogun awọn Fulani n gbona janjan ni Yewa, ti ha sọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun bayii o. Wọn lo lu awọn obinrin kan to fẹẹ fẹ ni jibiti owo nla, bẹẹ ko pada fẹ wọn, o kan lu wọn ni jibiti owo ati ara ni.
Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin yii, ni iroyin yii tẹ ALAROYE lọwọ, ẹsẹkẹsẹ la si ti pe Kabiyesi Adabọnyin lati gbọ tẹnu ẹ, ṣugbọn ọba naa ko gbe foonu, bẹẹ ni ko ka atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i.
Pẹlu fọto Adabọyin lagọọ ọlọpaa ni iroyin naa bọ sori ayelujara, ẹda iwe ti ọkan ninu awọn obinrin naa, Halima Oniru, si fi kan an, eyi ti ALAROYE ri, ṣalaye pe Kabiyesi Adabọnyin gba owo to to miliọnu lọna aadọjọ naira (150,000,000) lọwọ oun, lẹyin to ti ṣeleri pe oun yoo fẹ oun, ti ko si mu ileri naa ṣẹ.
Ẹsun ti obinrin to n jẹ Halima yii fi kan an tẹsiwaju pe ọpọ igba ni Adabọnyin gba owo lọwọ oun, ti yoo ni oun fẹẹ fi ṣe ọrọ ọlọba de (Baalẹ ni tẹlẹ ki ijọba Amosun too sọ ọ di ọba onipo kẹta lọdun 2019). Ọmọbinrin naa ṣalaye pe Adabọnyin fi owo to gba lọwọ oun gba otẹẹli tan ni, awọn obinrin alaimọkan bii toun ti wọn si n ko si i lọwọ lo n fowo naa gbe lọ si otẹẹli nla nla kaakiri.
Oriṣiiriṣii iwe ifisun lawọn ọlọpaa ti gba lori jibiti ọba yii gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
Yatọ si ẹsun yii, a tun gbọ pe ọba to gbọ afẹ daadaa, to si rẹwa yii, maa n mọ-ọn-mọ ya fọto pẹlu awọn eeyan nla nla lawọn ibi pataki, yoo si gbe e soju opo Fesibuuku ati Instagraamu rẹ, yoo maa fi fa oju awọn obinrin mọra, yoo si maa ṣeleri pe oun yoo fẹ wọn. Wọn ni ohun to maa n sọ fun wọn ni pe oun atiyawo oun ko si papọ mọ, o ti lọ.
Nigba ti ALAROYE ṣabẹwo saafin Adabọnyin, nijọba ibilẹ Ọdẹda, loṣu meji sẹyin, a ko ri Olori kankan laafin ọba yii, ṣugbọn o sọ fun wa pe ilu oyinbo toun ti waa jọba ni Naijiria ni awọn ọmọ oun wa, ko sọrọ nipa iyawo rẹ rara.
Lori ẹsun ti wọn fi kan an yii, ẹda iwe ti ọba yii fi fesi saafin Alake naa wa nikaawọ wa, nibẹ ni Kabiyesi Adabọnyin ti ṣalaye pe ibadọrẹ ọkunrin ati obinrin lo da oun ati obinrin yii pọ, o ni ololufẹ lawọn.( Ki i tun ṣe Halima, obinrin mi-in to pe orukọ ẹ ni Abilekọ Adebayọ ni.)
O fi kun un pe awọn owo to waa di ọran mọ oun lọwọ nitori ẹjọ Adebayọ yii ki i ṣe owo nla, owo keekeeke bii ẹgbẹrun mẹwaa, ogun ẹgbẹrun tabi ọgbọn ẹgbẹrun, to fi ṣe oun loore ni. O loun ko mọ bi wọn ṣe ṣi iru owo bẹẹ to fi pọ to miliọnu marun-un naira ti Abilekọ Adebayọ yii n beere lọwọ oun, nigba to jẹ owo ifẹ to wa laarin awọn ni, toun ko si fi ẹtan tabi ipa gba a lọwọ obinrin naa.
Olu Kemta yii tun sọ pe mọto toun naa wa lọwọ Adebayọ to n fẹsun kan oun yii. O ni mọto bọọsi alawọ buluu kan loun ya a pe ko maa lo o fun iṣẹ rẹ nigba tawọn ṣi jọ wa papọ . O ni obinrin naa ko da mọto ọhun pada titi doni.
Akọroyin wa pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lati mọ bi ọrọ yii ṣe jẹ gan-an nipa ti Halima ati Adebayọ pẹlu awọn obinrin mi-in ti wọn ni wọn ti n fi ẹjọ ọba yii sun tipẹ, ṣugbọn niṣe loun naa ko gbe ipe rẹ, ko si fesi si atẹranṣẹ pẹlu.