Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori iku ọmọdekunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Victor Ọlọnade, to pokunso sẹyinkule ile wọn niluu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun.
Victor, ẹni ti wọn pe ni akẹkọọ Ipetu Ijeṣa College of Technology, la gbọ pe o kuro nileewe laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, to si pe iya rẹ lori foonu pe ọrọ pataki kan wa.
Nigba to dele wọn to wa ni Ojule kọkandinlaaadọta agbegbe Iṣokun, niluu Ileṣa, ko ba iya rẹ ninu ile, ko si ba ẹnikẹni sọrọ tabi fu ẹnikẹni lara ninu awọn alajọgbele wọn titi to fi pokunso pẹlu waya tẹlifoonu ti wọn fi n ṣaṣọ lẹyinkule.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọkunrin kan, Agboọla Oluṣọla, lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan ọjọ Satide naa.
Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe nigba tawọn ọlọpaa debẹ, wọn ba oku Victor lọrun waya, ko si si apa (mark of violence) kankan lara rẹ.
O ni awọn ti gbe oku rẹ lọ sile igbokuu-pamọ-si ti ileewosan Wesley Guild, niluu Ileṣa, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ abami naa.