Florence Babaṣọla, Osogbo
Ọkunrin awakọ akoyọyọ kan, Olumide Adesina, ti wọ ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Baba Alkali ati kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, lọ sile-ejọ giga ilu Ileefẹ lori iku to pa ọmọ rẹ, Olufẹmi Oriyọmi, sinu agọ ọlọpaa kan n’Ifẹ.
Yatọ si Alkali ati Ọlọkọde, baba yii tun wọ Supol Isaac Ọmọyẹle, Inspẹkitọ Ọmọboriowo, Inspẹkitọ Lekan ati ọọfisa kan ti wọn n pe ni Baba Bolu, lọ si kootu.
Ninu iwe ipẹjọ to ni nọmba HIF/30/22, ni Baba Fẹmi ti rọ kootu lati paṣẹ fun olujẹjọ lati san miliọnu lọna aadọta Naira lori esun pe wọn ti i mọle lọna aitọ, wọn fiya jẹ ẹ titi to fi gbẹmi-in mi.
Bakan naa ni Adeṣina sọ fun kootu lati paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa yọnda oku ọmọ oun ti wọn gbe sọdọ.
Ninu iwe ipẹjọ naa, Adeṣina sọ pe ọmọkunrin kan, Kẹhinde Ọlayade, ti awọn ọlọpaa mu pẹlu Fẹmi, sọ lẹyin ti wọn tu u silẹ pe iya to pọ lawọn jẹ lakata wọn.
O fi kun ọrọ rẹ pe ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii lawọn ọlọpaa ko Ọlayade, Raimi Sheriff ati Olufẹmi lagbegbe Safẹjọ, niluu Ileefẹ, lori ẹsun pe wọn n ṣe jibiti ori ẹrọ ayelujara.
Inu atimọle yii ni Fẹmi, ẹni ọdun mọkanlelogun, wa to fi bẹrẹ aisan latari iya ojoojumọ to n jẹ nibẹ, wọn ko si mojuto o titi to fi dakẹ sibẹ.
Adeṣina sọ siwaju pe Ọlayade sọ pe ojoojumọ ni wọn n fi idi ati ada lu awọn mẹtẹẹta lati le parọ mọra wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
O ni, “Wọn fi sẹkẹsẹkẹ si wọn lọwọ ninu akolo ti wọn ju wọn si, bẹẹ ni ẹjẹ n jade ni gbogbo ara wọn. Inira yii pọ fun Fẹmi ti ko le jokoo, sibẹ, awọn ọlọpaa ko dahun.
“Lalẹ ọjọ naa, Fẹmi ko le sun, gbogbo awọn ti wọn wa ninu atimọle ni wọn n ba a sunkun nitori inira to n la kọja, ko le jẹun, ko le tọ, ko le da yagbẹ titi di ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
“Lọsan-an ọjọ Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti inira yii pọ fun Fẹmi ni awọn ọlọpaa mu un jade, ṣugbọn alọ rẹ ni wọn ri latinu atimọle, wọn ko ri abọ rẹ, ọmọkunrin naa pada ku.”