Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Latari bi awọn Fulani darandaran ṣe ṣakọlu si awọn olugbe ilu Gbabu/Bala, nijọba ipinlẹ Aṣa, nipinlẹ Kwara, awọn ọlọpaa ti gbakoso agbegbe naa ki alaafia le jọba.
ALAROYE gbọ pe aṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni awọn Fulani darandaran ṣe akọlu si arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Akeem Ajapẹ Ajẹfẹdo ninu oko rẹ, ti wọn si fi ada ṣa a, yannayanna. Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, Ajapẹ wa nileewosan to ti n gba itọju.
Bakan naa la tun gbọ pe awọn Fulani darandaran ọhun tun ṣeku pa eeyan mẹta niluu Faje/Ọtẹ, nijọba ibilẹ Aṣa yii kan naa. Eyi lo ṣokunfa bi awọn olugbe agbegbe naa ṣe fi ija pẹẹta pẹlu awọn Fulani, ti ibẹru bojo si gbilẹ ni agbegbe naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti waa bẹnu atẹ lu akọlu naa, o waa sọ pe awọn yoo fi janduku ti awọn ba gba mu jofin. O tẹswaju pe lotitọ, awọn ko ti i ri ẹnikankan mu, ṣugbọn awọn ọlọpaa ti gbakoso agbegbe naa ki alaafia le jọba.