Awọn ọlọpaa ti mu Portable olorin, Eleweeran ni wọn gbe e lọ

Jọkẹ Amọri 

Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọmọkunrin olorin taka-sufee nni, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, ti gbogbo eeyan mọ si Portable tabi Zah Zuh olorin. Ba a ṣe n kọ iroyin yii, atimọle ọlọpaa, ni Eleweran, niluu Abẹokuta lo wa.

 Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu ọmọkunrin olorin taaka-sufee naa. Awọn agbofinro ni lẹyin wakati mejilelaaadọrin ti awọn ọlọpaa fun un pe ko fi waa fi ara rẹ han niwaju awọn lori ẹsun itọninija ti wọn fi kan an ti ko yọju lawọn lọọ fi ọwọ ofin mu un.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta yii, ni wọn mu Portable, ti wọn si da a duro sagọọ wọn ni Eleweran, niluu Abẹokuta. Wọn ni ibẹ ni yoo wa titi di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti wọn yoo gbe e lọ sile-ẹjọ.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni ọmọkunrin olorin to saaba maa n pariwo, ‘wahala wahala wahala’ yii wa lakata awọn ni Eleweran, niluu Abẹokuta.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni awọn agbofinro ya bo ile igbafẹ rẹ, ti wọn ni awọn fẹẹ ri i lagọọ awọn lori awọn ẹsun kan ti wọn fi kan an, ṣugbọn wahala ni ọmọkunrin naa da bolẹ pẹlu awọn ọlọpaa. Eyi lo fa a ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa patapata niluu Abuja, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi fi kede pe awọn n wa ọkunrin naa, awọn yoo si fọwọ ofin mu un.

Leave a Reply