Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Kọmandi ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti ranṣẹ pe ẹni to ni Otẹẹli Pavilion, eyi to wa ni Ayepe, nijọba ibilẹ Odogbolu, nipinlẹ Ogun, nitori kamẹra ti wọn fi si yara awọn alejo lai jẹ pe awọn to n sanwo lo yara naa mọ rara.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe Eko lẹni to ni otẹẹli yii n gbe, o lawọn ti ranṣẹ pe e lati waa ṣalaye idi ẹ to fi faaye gba kamẹra ti yoo maa ka gbogbo ohun tawọn alejo ba ṣe ni yara ti wọn sanwo fun silẹ, nitori eyi lodi labẹ ofin.
Ṣe lopin ọsẹ to kọja yii ni fidio kan gun ori ayelujara, nibi ti ọkunrin kan ti n fibinu sọrọ, to si n ja awọn kamẹra ti wọn fi sinu awọn yara otẹẹli yii nikọọkan.
Ọkunrin naa n sọrọ pẹlu ibinu, o ni awọn ara otẹẹlu yii ti ri ihooho ẹgbọn oun, bẹẹ ni wọn ri ti iya oun pẹlu, nitori awọn eeyan oun naa ti gba yara ninu otẹẹli naa ti wọn sun sibẹ, wọn ko si mọ pe kamẹra wa loke yara ti kaluku wọn n sun, to n ka ihooho wọn silẹ gedegbe.
Kamẹra mẹrin lọkunrin naa ti tu kalẹ to si fi han ninu fọnran fidio naa, ẹlẹẹkarun-un lo n tun lọwọ lasiko to n ṣe fidio ọhun, bẹẹ lawọn eeyan wa nibẹ, ti kaluku n sọ pe titẹ ẹtọ onibaara loju mọlẹ ni ohun ti awọn ara otẹẹli Pavilion yii n ṣe, awọn yoo si gbe orukọ wọn saye pẹlu pinpin fidio naa kiri.
Ni bayii ṣa, fidio naa ti de ọdọ awọn ọlọpaa, wọn si ni kẹni to ni in waa ṣalaye idi to fi jẹ ki kamẹra wa ni yara alejo, nigba to jẹ ofin ko faaye gba iru ẹ nilẹ wa.