Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọmọ igbimọ majẹ-o-bajẹ ilu Ikirun ti wọn n pe ni Akinrun-in-Council, ti ke si Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, lati pa ohun da lori iyansipo Ọlalekan Akadiri tijọba gbe ọpa aṣẹ fun gẹgẹ bii Akinrun ti ilu Ikirun, wọn ni ko rọ ọ loye kia.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lorukọ awọn ọmọ igbimọ ti wọn jẹ ọgọrin ninu mejidinlaaadọrun-un, Ọjọgbọn Yakub Fabiyi ṣalaye pe bi Oyetọla ṣe yan Akinrun tuntun lai fi ti ẹjọ to wa ni kootu ṣe jẹ titapa si aṣẹ ile-ẹjọ.
O waa gba gomina niyanju lati ṣe ohun to tọ, ko ma baa fi ọwọ pa ida ofin loju, ko si tete yọ Ọba Akadiri kuro nipo naa.
Ọjọgbọn Fabiyi sọ siwaju pe “A fẹ kijọba yọ Akinrun tuntun yii nitori iyansipo rẹ ko ba ilana aṣa wa niluu Ikirun mu. Niluu Ikirun, a ki i dibo yan ọba. Eesa ni yoo ko awọn afọbajẹ to ku sodi lati beere lọwọ Ifa, ẹni ti ifa ba si mu naa ni wọn yoo fi jọba.
“Akọsilẹ ilana oye jijẹ kan tun wa nilẹ to ṣalaye bi awọn idile ọlọmọọba yoo ṣe ma jẹ Akinrun ni ṣisẹ-n-tẹle. Idile mẹta lo n jọba: Ile Ọbaara, ile Adedeji ati ile Gbolẹru. Ile Ọbaara ni Adeyẹmi, Akinrun ijẹta ti wa, ile Adedeji ni Ọlayiwọla to gbesẹ ti wa, nitori naa, ile Gbolẹru lo kan lati fa ọmọ oye silẹ, awọn idile Gboléru si ni oniruuru ẹjọ ni kootu lọwọlọwọ.
“Ni awọn ilu to wa nilẹ okeere, ti ọrọ kan ba ti wa nile-ẹjọ, ẹni to ba gbe igbesẹ kankan le e lori yoo de ọgba ẹwọn. Laipẹ yii, kootu ju alaga ajọ EFCC sọgba ẹwọn nitori pe o huwa to ta ko aṣẹ ile-ẹjọ. Ohun ti gomina ṣe ta ko ofin, o si gbọdọ wẹ ara rẹ mọ nipa rirọ Akinrun loye.
Nigba to n sọrọ lori ẹsun naa, Kọmiṣanna fun eto iroyin atilanilọyẹ, Funkẹ Ẹgbẹmọde, sọ pe ijọba ko gbe igbesẹ kankan ta ko ofin lori ọrọ yiyan Akinrun tuntun.
O ni gbogbo awọn ilu ti ko ni ọba lawọn gbe igbesẹ finnifinni lori ohun ti awọn araalu ba sọ pe awọn fẹ.
Ẹgbẹmọde sọ siwaju pe ko si iwe kootu kankan to ka ijọba lapa ko lori yiyan Akinrun tuntun.