Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn kan ti wọn fura si bii ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe ṣa ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan, Quadri Ọlalekan, pa.
ALAROYE gbọ pe , irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe Oluguna, niluu Oṣogbo. Ṣe lawọn ọkunrin bii mẹfa yọ si Quadri lojiji, ti wọn si bẹrẹ si i ṣa a.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri sọ pe ṣe lawọn eeyan ọhun ṣọ Quadri debẹ pẹlu oniruuru awọn nnkan ija lọwọ.
Ọkunrin yii fi kun un pe bi wọn ṣe yọ si Quadri lo bẹrẹ si i bẹ wọn pe ki wọn ṣaanu oun, ṣugbọn awọn eeyan naa ko gba, ṣe ni wọn bẹrẹ si i gun un.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe iwadii ti fi han pe ọmọkunrin kan, Afeez, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Terror, lo ko awọn eeyan rẹ ti wọn fura si bii ọmọ ẹgbẹ okunkun lọọ dena de Quadri, ti wọn si pa a.
Ọpalọla sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, o ni gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu iku ọmọkunrin naa ko ni i lọ lai jiya.