Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ko din ni meji ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn fara gbọta ibọn lakooko tawọn ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi ipinlẹ Ekiti, atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa doju ija kọ ara wọn laduugbo Omiṣanjana, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii, niluu Ado-Ekiti.
Lasiko ija ajaku akata to waye fun bii ọgbọn iṣẹju gbako ọhun, ko din ni meji lara awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun naa tọwọ awọn sifu difẹnsi tẹ, ti wọn si ti wa lakata awọn ọlọpaa bayii, nibi ti wọn ti n sọ tẹnu wọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọga agba ajọ ọhun nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni John Fayẹmi, ṣalaye fawọn oniroyin nipa iṣẹlẹ naa pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa jẹ ọmọ ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ.’
Orukọ awọn meji ti ọwọ tẹ naa, ti ọkan lara wọn jẹ obinrin, ti ekeji si jẹ ọkunrin ni, Tiwatọpẹ Oluwafẹmi, ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Bọla Ọlọrunfẹmi, ọmọọdun mẹrindinlogun. O lawọn ẹlẹgbẹ wọn yooku doju ija kọ awọn ọmọ sifu difẹnsi naa pẹlu ibọn lakooko ti wọn fẹẹ lọọ mu wọn ni ibuba wọn to wa laduugbo Omiṣanjana, ni Ado-Ekiti.
O fi kun un pe lakooko ija naa, awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn tun jẹ ajinigbe ọhun, ni wọn ji obinrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan gbe ni adugbo naa, ẹni yii lawọn lawọn ẹṣọ ọhun fẹẹ lọ doola ẹmi rẹ ti wọn fi wọn ṣadeede doju ibọn kọ wọn, eyi to mu ki meji lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fara gbọta, ti wọn si ti n gba itọju nileewosan kan to jẹ ti ijọba to wa ni Ado-Ekiti. Awọn meji tọwọ tẹ wa lahaamọ awọn agbofinro.
A gbọ pe awọn afurasi ọdaran naa ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun pọmbele lawọn, awọn lawọn si n da agbegbe Mathew ati Omiṣanjana laamu latẹyinwa.
O fi kun un pe awọn ọdaran naa jẹwọ pe awọn ti ṣe akọlu loriṣiiriṣii bii idigunjale, ifipabanilopọ, si awọn eeyan agbegbe naa, ki ọwọ awọn agbofinro too tẹ awọn.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ti n gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ki ọwọ awọn le tẹ awọn ọdaran to ku.