Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo awọn to gbọ iru iku ti wọn fi pa ọkunrin kan niluu Oṣogbo lọrọ naa n ṣe ni kayeefi, ti wọn si n beere pe iru ẹṣẹ wo ni ọmọkunrin naa le ṣẹ wọn ti wọn fi pa a, ti wọn ge ẹsẹ rẹ lọ, ti wọn ṣẹṣẹ waa dana sun oku rẹ, ti wọn si lọọ ju ajoku oku naa saakitan
Ko ti i ṣeni to mọ ohun ti baale ile naa ṣe fun awọn apaayan ti ẹnikan ko ti i mọ bayii, ṣugbọn ti wọn fura si bii ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn baale ile kan torukọ rẹ n jẹ Waheed Abioye, to jẹ alabaarin alaga ẹgbẹ awakọ NURTW, ẹka ijọba ibilẹ Oṣogbo ati Ọlọrunda, iyẹn Kazeem Oyewale.
Alaroye gbọ pe lẹyin ti awọn eeyan yii pa Waheed tan, wọn dana sun oku rẹ, wọn si ko ajoku rẹ da sori ile idalẹsi kan (Refuse dump) lagbegbe Arikalamu, niluu Oṣogbo.
Ibudokọ to wa ni Oju’rin, niluu Oṣogbo, lọmọkunrin naa ti n ṣiṣẹ, ọmọ bibi Isalẹ Ọṣun, niluu naa si ni.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Ọpalọla sọ siwaju pe aago mẹwaa alẹ ku ogun iṣẹju ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun yii, lawọn olugbe agbegbe Arikalamu, niluu Oṣogbo, fi to awọn ọlọpaa leti pe awọn ọkunrin kan ti wọn dihamọra ogun gbe ajoku Waheed wa sile idalẹsi kan to wa nibẹ.
O ni wọn dana sun un, o si jona debii pe iyawo rẹ nikan lo da a mọ, bẹẹ ni wọn tun ge ẹsẹ ọtun rẹ lọ. O sọ siwaju pe awọn oṣiṣẹ eto ilera ijọba ibilẹ Ọlọrunda ni wọn gbe ajoku rẹ lọ sile igbokuu-si ti ọsibitu UNIOSUN, niluu Oṣogbo.
Ọpalọla sọ siwaju pe iwadii n lọ lọwọ lati le mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa, ki wọn le fimu kata ofin.