Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun paayan kan lasiko ti wọn kọju ija sira wọn

Adewale Adeoye

Ṣe lọrọ  di bo o lọ o yago ni aṣalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla yii, lagbegbe Ozoro, nijọba ibilẹ Isoko-North, nipinlẹ Delta, lakooko tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan doju ija kọra wọn, ti wọn si da ẹmi ẹni kan legbodo. Ṣa o, awọn ọlọpaa lawọn ti fọwọ ofin mu mẹrin lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn da wahala nla naa silẹ laarin ilu ju sahaamọ awọn bayii.

ALAROYE gbọ pe ija agba meji lo waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ati Viking, laarin ilu naa, ni wọn ba bẹrẹ si i ba aara wọn fa wahala, bẹẹ ni ibọn n ro lakọlakọ, kawọn eeyan agbegbe ibi ti iṣẹlẹ  ọhun ti waye si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti bẹrẹ si i fibọn le ara wọn kaakiri ilu naa.

Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki ọpọ oniṣowo to ni ṣọọbu lagbegbe ọhun maa sare palẹmọ ọja wọn, kawọn ọmọ ita ma baa lo anfaani ọhun lati ja wọn lole ọja wọn.

Ọkan lara awọn ọdẹ aduugbo ọhun to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ, ṣugbọn ti ko darukọ ara rẹ sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye lagbegbe ọhun laaṣaalẹ ọjọ Aje, ọsẹ yii, ṣugbọn ẹni kan pere lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lo ku, ki i ṣe meji tabi mẹta tawọn kan n sọ kaakiri.

Bakan naa lo ni awọn ọlọpaa ti wọn pe ti pana wahala ọhun, ti wọn si ti fọwọ ofin mu mẹrin lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ri lagbegbe naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Bright Edafe, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe oun ti gbọ si iṣẹlẹ naa, o ni eeyan kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji ti wọn n ja lo ku, nigba tawọn ọlọpaa si ti fọwọ ofin mu mẹrin lara wọn.

Siwaju si i, alukoro ni awọn maa too bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ naa, tawọn si maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn  to ba lọwọ ninu ija buruku ọhun.

Leave a Reply