Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun paayan mẹta, wọn gbe oku wọn sa lọ l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹta ni wọn pade iku ojiji niluu Ọwọ, ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ọwọ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

ALAROYE gbọ pe wọn yinbọn pa awọn eeyan ọhun ninu ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye niluu naa lalẹ ọjọ iṣẹlẹ yii.

Nibi to le de, wọn ṣi n wa oku awọn ti wọn pa yii, ti wọn ko si ti i mọ ibi ti wọn wa ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ. Wọn ni awọn janduku ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kọ lati fi oku wọn silẹ, nitori lẹyin ti wọn yinbọn pa wọn tan ni wọn tun wọ oku wọn lọ sibi ti ẹnikẹni ko ti i mọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin, Olubadamọran fun gomina lori eto aabo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ, ni awọn Amọtẹkun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wa nikalẹ lati bojuto eto aabo niluu Ọwọ.

Adelẹyẹ to jẹ ọga Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ondo, ni igbesẹ ti n lọ labẹnu lati ri awọn oniṣẹẹbi naa mu nibi yoowu ki wọn le fara pamọ si.

Alukoro Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ṣalaye pe awọn ọlọpaa to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ondo ti lọ sibi iṣẹlẹ ọhun lati peṣe aabo fawọn araalu.

Leave a Reply