Awọn ọmọ iya kan naa fipa ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo pọ nibi to ti n wẹ lodo n’Ifọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ Oluwaṣeun Damilohun ati Oriyọmi Damilohun ti wọn jẹ ọmọ iya ati baba kan naa, pẹlu ọrẹ wọn, Oluwaṣẹgun Idowu, fun pe wọn fipa ba ọmọbinrin tọjọ ori ẹ ko ju mẹ́rìndínlógún(16) lọ lo pọ l’Odo Pata, labule Pata Abiọdun, nijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun.

Oṣiṣẹ ajọ So-Safe kan, Alimi Ọlasunkanmi, lo fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti pe nigba tọmọbinrin naa lọọ wẹ lodo yii ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ Ọjọruu, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa, yii, ni awọn gende mẹta naa dena de e, ti wọn si fipa wọ ọ wogbo to wa nitosi, bi wọn ṣe bẹrẹ si i ba a lo pọ nikọọkan niyẹn titi tawọn mẹtẹẹta fi tẹ ara wọn lọrun.

Bi wọn ti n ṣere egele naa lọwọ ni ọkan ninu wọn n fi foonu rẹ fidio ibalopọ ohun, bẹẹ ni wọn lo n sọ fọmọbinrin ọhun pe awọn yoo ju fidio naa sori ẹrọ ayelujara ni to ba fi le sọ ohun to ṣẹlẹ fọlọpaa abi fun ẹnikẹ́ni.

Ṣugbọn ọmọbinrin naa ko fi ti ihalẹ wọn
ṣe rara, ko pẹ ti iṣẹlẹ naa fi de teṣan ọlọpaa Ifọ, wọn si wa awọn afipabanilopọ naa ri, wọn mu wọn ṣinkun.

Awọn mẹtẹẹta ni wọn jẹwọ pe awọn fipa ba ọmọbinrin naa sun loootọ, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi. Wọn si ti gbe ọmọ ti wọn ṣe baṣubaṣu naa lọ sọsibitu.

Bakan naa ni CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn afipabanilopọ yii lọ si ẹka to n ri si ẹsun bii eyi. O si gba awọn obi nimọran pe ki wọn kilọ fawọn ọmọ wọn nibi iwakiwa, nitori ọmọ to ba ṣẹ sofin yoo jiya ofin.

 

 

 

One thought on “Awọn ọmọ iya kan naa fipa ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo pọ nibi to ti n wẹ lodo n’Ifọ

Leave a Reply