Faith Adebọla
Ọwọ palaba awọn ọmọ orileede Naijiria meje kan ti segi nidii okoowo egboogi oloro gbigbe, awọn agbofinro si ti sọ wọn sahaamọ bayii. Amọ nibi tọrọ naa le si ni pe ki i ṣe Naijiria ni wọn ha si, ilẹ okeere ni, lorileede kan ti wọn n pe ni Seychelles.
Aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria to n gbe lorileede Seychelles, Ọgbẹni Mathias Adidi, lo kegbajare iṣẹlẹ yii lori ẹrọ abẹyẹfo, tuita rẹ, to si fi ṣọwọ sori ikanni akọroyin ileeṣẹ Tẹlifiṣan Arise kan, bẹẹ lo fi fọto awọn afurasi ọdaran naa sibẹ, nibi to ti beere pe, ‘ta lẹni to wa ni Naijiria, to n ran awọn eeyan yii niṣẹkiṣẹ bii eyi, awọn eleyii ti ha siluu oyinbo nibi o, egboogi oloro ni wọn gbe wọlu, wọn si ti mu wọn.
‘Mo fẹẹ kẹ ẹ wo wọn, kẹ ẹ sọ fun awọn eeyan wọn nile ti wọn o ba ti i gbọ o, ẹ ba wa sọ fawọn olokoowo buruku ti wọn n ran awọn ọmọ wọnyi niṣẹ gbigbe egboogi oloro kiri o, tori o ti n di lemọlemọ bayii, awọn meje ti wọn ṣẹṣẹ mu lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọjọ, oṣu Kẹfa, to kọja yii, re e. Inu ewu gidi ni wọn wa bayii.’
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ko darukọ wọn, bẹẹ ni ko sọ ewu ti wọn wa ninu rẹ, boya ti ẹwọn ni abi iku, sibẹ, o fi aidunnu rẹ han pe ko dara b’awọn eeyan kan ṣe n fi egboogi oloro ran ọmọlakeji wọn lọ siluu oyinbo, o ni nnkan abamọ ni aṣa naa jẹ, tori ofin atawọn eeyan orileede naa ki i fọwọ rirọ mu iru ẹsun bẹẹ.