Faith Adebọla, Eko
Afi bii igba tawọn apẹja n fi awọn wọn kore ẹja, bẹẹ lajọ to n gbogun tiwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC, n fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi ọdaran ti wọn yan ṣiṣe jibiti ori ẹrọ ayelujara laayo, awọn ọmọ ‘yahoo’ mejilelọgbọn lọwọ ajọ naa tẹ lọjọ Aje, Mọnde yii, wọn ti n jẹwọ ẹṣẹ wọn fawọn agbofinro.
Orukọ awọn afurasi naa ni Waris Adediran, Ọlasunkanmi Oluwabunmi Oni, Adeoye David, Godwin Ifeanyi, Tunde Ọlabire, Mike Oiseomaye, Anthony Nicholas, Adebayọ Ọbabire, Ebuka Nwosu, Udenta Obiora, Quadri Yusuf, Shedrack Idoko, Andrew Agbai, Mercy Adedoyin ati Ọlamide Mubarak.
Awọn to ku ni Charles Maduabuchi Oli, Usman Shittu, Junior Salami, Damilare Babalọla, Idris Mutairu, Micheal Adebiye, Ọlawaye Ọlayẹmi, Idris Amodu, Ahmed Adeniyi, Chibueze Okafor, Damilare Morounfayọ, Micheal Makanjuọla, Samuel Oyindamọla, Haruna Mubarak Okiki, Ọpẹyẹmi Hassan, Idris Adaṣọfunjo ati Rasak Adaṣọfunjo ti wọn jẹ tẹgbọn-taburo.
Olobo kan lo ta ajọ EFCC, ẹka ti Eko, nipa irin awọn afurasi yii, wọn lawọn aladuugbo kan lo tẹ ajọ naa laago, lawọn agbofinro ba ka wọn mọ ile kan ti wọn fi ṣe ibuba wọn ni Plot 12, Road 2, Goodnews Estate, laduugbo Ṣangotẹdo, lọna Lẹkki si Ajah. Awọn mọkandilogun la gbọ pe ọwọ ba nibẹ.
Inu ile kan to wa ni Chevyvies Estate, lọna Chevron, lagbegbe Lẹkki yii kan naa lọwọ ti ba awọn to ku.
Gẹgẹ bi Alukoro ajọ naa ṣe sọ, Ọgbẹni Wilson Uwajuremi sọ pe ọpọ kọmputa alaagbeletan, foonu, awọn nnkan eelo abana-ṣiṣẹ ati oogun abẹnu gọngọ lawọn ka mọ awọn afurasi wọnyi lọwọ.
O ni gbogbo wọn ti n ṣalaye ara wọn fun ẹka to n ṣiṣẹ iwadii, ati pe laipẹ lawọn yoo taari wọn siwaju adajọ.