Jide Alabi
Awọn ̀ọmọ Yoruba ti wọn n gbe loke-okun ti kora wọn jọ bayii lati fatilẹyin wọn han fun Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, bẹẹ ni wọn ti kilọ fun ijọba apapọ ati ti ipinlẹ, ki wọn ma wa ohun ti ko sọnu si ọkunrin naa lẹsẹ.
Lati awọn orilẹ-ede bii London, America, Canada lawọn eeyan ọhun ti kora wọn jọ, ti wọn si sọ ninu atẹjade ti Ọgbẹni Kamil Lamidi ati Dokita Leke Otunuga fọwọ si pe awọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu Sunday Igboho lati fi ko Yoruba yọ kuro ninu ajaga awọn Fulani.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti sọ pe, “A ti ṣepade pẹlu Oloye Sunday Igboho, bẹẹ la ti ṣeleri pe gbọn-in gbọn-in la wa lẹyin ẹ lori iṣẹ ribiribi to gbe dani yii lati daabo bo ilẹ Yoruba, nigba ti awọn oloṣelu to yẹ ki wọn ṣe e ti ja wa kulẹ, ti wọn ko tẹle ileri wọn.”
Ninu koko nnkan mẹrin ti wọn duro le lori bayii ni wọn ti sọ fun ijọba ipinlẹ ati apapọ pe ki wọn tete jawọ lori bi wọn ṣe fẹẹ mu Sunday Igboho. Wọn ni dipo bẹẹ, niṣe lo yẹ ki ijọba bẹrẹ si i sa ipa ẹ lori bi yoo ṣe mu awọn alejo ọran ti wọn ti di wahala si ilẹ Yoruba, ti wọn ti di janduku afẹmiṣofo, ti wọn n fi maaluu ba nnkan oko jẹ, ti wọn n paayan, ti wọn tun n fipa baayan lo pọ kaakiri ilẹ Yoruba.
Bẹẹ ni wọn tun sọ pe Sunday Igboho nikan kọ lo wa ninu ija yii, awọn paapaa ti kun un, awọn jọ n ja fun itusilẹ ilẹ Yoruba ni. Bẹẹ ni wọn tẹnu mọ ọn pe ti wọn ba fi le mu un, ọrọ ọhun yoo di wahala gidi si ijọba lọrun.
Siwaju si i, awọn ọmọ Yoruba yii tun sọ pe ko saaye ki awọn Fulani maa da ẹran jẹ kiri loru mọ kaakiri ilẹ Yoruba, ati pe ijọba gbọdọ sọ ọ dofin. Bakan naa ni wọn sọ pe eto gbọdọ wa fun igbesẹ ‘gba ma binu’ fun awọn ti wọn ba ba nnkan oko wọn jẹ, awọn ti wọn ti pa nipakupa atawọn ti wọn ti huwa ti ko tọ si.
Bakan naa ni wọn tun ke si gbogbo ọmọ Yoruba kaakiri agbaye lati dide ja fun ilẹ Yoruba pẹlu gbogbo nnkan ti wọn ba ni labẹ ofin. Wọn waa rọ awọn gomina ilẹ Yoruba lati fọwọsowọpọ, ki ilẹ Yoruba le tubọ tẹsiwaju daadaa.