Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọkan lara awọn baalẹ ilu Patigi, Liman Umar Mohammed, sọ pe iyawo meji atawọn ọmọ bii marun-un ni baale ile kan padanu sinu iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to fẹmi aadọjọ eeyan ṣofo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niluu Patigi, nipinlẹ Kwara. Yatọ si iyẹn, o ni mọlẹbi kan wa to padanu eeyan mẹwaa.
Mohammed Hassan, gende-kunrin tori ko yọ nibi iṣẹlẹ naa ṣalaye pe nigba tawọn n dari bọ lati ibi ayẹyẹ igbeyawo nijamba ọhun waye. O ni ọkọ oju omi ọhun ko ti i rin ju idaji kilomita lọ to fi kọsẹ, lẹyin to kọsẹ tan lawọn agbaagba to wa ninu ọkọ sọ fun awọn ọdọ pe ki wọn maa bẹ sinu odo lati luwẹẹ nitori awọn ko mọ ohun tawọn le ṣe mọ nigba ti ọkọ naa ti fẹẹ maa ri sinu alagbalugbu omi. O tẹsiwaju pe ọpọ awọn ti ko le luwẹẹ ni ko bẹ sinu omi, wọn jokoo bi ọkọ naa ṣe n ri lọ. Eyi to buru nibẹ ni pe ọpọ obinrin lo ku lasiko ti wọn fẹẹ doola ẹmi ọmọ wọn.
Ẹlomiiran tori ko yọ nibi iṣẹlẹ yii kan naa, Abilekọ Aisha Mohammed, sọ pe inu ọfọ nla ni oun wa bayii latari pe awọn ọmọbinrin oun mẹta ti wọn n mura lati lọ sile-ọkọ ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ. Titi digba ta a n ko iroyin yii jọ ni wọn si n wa awọn to ri sinu omi ọhun.
Gomina ipinlẹ Kwara, to tun alaga awọn gomina nilẹ yii, Abdulraman AbdulRazaq, ti ṣabẹwo siluu Patigi, ti iṣẹlẹ naa ti waye, o kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi tọrọ kan, o jẹjẹẹ pe oun yoo fun awọn to n rinrin-ajo lori omi niluu ọhun ni jakẹti ẹgbẹrun kan ti wọn yoo maa lo lati fi daabo bo ara wọn.