Awọn ọmọlẹyin Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla ni wọn n da wahala silẹ laarin wọn-Akere

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ọṣun lasiko iṣejọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, Ọnarebu Sunday Akere, ti sọ pe awọn arijẹ nidii mọdaru ni wọn n lulu ọtẹ laarin Gomina Oyetọla ati Arẹgbẹṣọla.

Lasiko ti Akere n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ṣalaye pe ko si ija tabi ọtẹ kankan laarin awọn oloṣelu mejeeji, bẹẹ ni wọn si bọwọ fun ara wọn.

O ni awọn ọmọlẹyin ti wọn n wa ojurere lọdọ Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla ni wọn n sọ ahesọ kaakiri pe aarin awọn mejeeji ko gun.

Gẹgẹ bi Akere ṣe sọ, “Ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa lawọn mejeeji, ẹkọ oṣelu kan naa ni wọn ni, Arẹgbẹṣọla lo pilẹ iṣejọba ti a n jẹgbadun rẹ lọwọlọwọ nipinlẹ Ọṣun, ko si le gba ko wo lulẹ.

“Ọmọ Imaamu ni Gomina Oyetọla, oniwa irẹlẹ si ni, ko le gba ki ede aiyede waye laarin ẹni to yan an gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ lọọfiisi gomina, wọn mọ bi wọn ṣe n yanju aawọ to ba fẹẹ waye nigbakuugba.”

Ni ti eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ, eleyii ti awọn kan si n sọ pe wahala aarin Oyetọla ati Arẹgbẹṣọla lo fa a, Akere ni irọ to jinna soootọ ni.

O ni ko si ipinlẹ kankan lorileede Naijiria ti ko foju winna wahala eto aabo, bẹẹ ni awọn ti wọn n da wahala naa silẹ ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu oṣelu tabi oloṣelu rara.

Lori bi awọn kan ṣe n pe fun idasilẹ orileede Oodua, Akinrogun ti ilu Igbajọ yii sọ pe ijọba apapọ ni lati tete wa nnkan ṣe sọrọ naa ko to di pe adabọrun yoo di ẹwu.

O ni wahala to n ṣẹlẹ kaakiri orileede yii ti pọ ju, o si le mu ki awọn araalu binu, ṣe lo si yẹ kijọba apapọ atawọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba pe awọn ti wọn n pe fun idasilẹ orileede Oodua yii, ki wọn jọ ni apero, ki wọn si fi ori ikoko sọọdunrun-un.

Akere fi kun ọrọ rẹ pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari ri ara rẹ bii Aarẹ gbogbo Naijiria, ki i ṣe Aarẹ awọn ẹya kan, ko maa ṣe deede laarin gbogbo ẹya to wa lorileede yii, ko si wa nnkan ṣe si ọrọ-aje to ti dẹnukọlẹ.

 

Leave a Reply