Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Amudat Babatunde ati Jamiu Oyetunji ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Sunday Igboho yoo tun foju ba kootu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla yii, lori ẹsun pe Amudat fi ẹka Fesibuuku rẹ kede ipaya faye, Jamiu ni tiẹ si ni awọn nnkan ija oloro lọwọ.
Ẹsun marun-un ọtọọtọ ni ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ijọba ti i ṣe DSS fi kan awọn meji yii. Wọn ni bi Amudat to jẹ obinrin kan ṣoṣo ninu awọn ọmọọṣẹ Igboho ti wọn ko lọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2021, ṣe n fi ẹka Fesibuuku rẹ kede ohun to n ṣẹlẹ nile ọga ẹ lọjọ naa lodi sofin.
Bẹẹ ni wọn ni Jamiu Oyetunji kun fun kiki nnkan ija oloro tawọn afẹmiṣofo n lo.
Ṣugbọn ọkan ninu awọn agbẹjọro awọn olujẹjọ yii, Sunday Adebayọ, sọ pe ẹjọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni ijọba pe ta ko awọn onibaara oun.
O lo da oun loju gidi pe awọn ọmọ ẹyin Igboho meji yii yoo jare bọ ni kootu ni, nigba ti Adajọ Obioria Egwuatu ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja ba gbọ ẹjọ naa lọjọ Mọnde.
Ṣe ṣaaju ni adajọ yii kan naa ti paṣẹ pe ki wọn faaye beeli silẹ fawọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho yii, ṣugbọn ti awọn to yẹ ko tu wọn silẹ ko ṣe bẹẹ fun igba pipẹ.
Nigba ti wọn si jaja tu awọn yooku silẹ, wọn ko fi Amudat ati Jaimu yii silẹ rara titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, iyẹn lẹyin ti wọn ti lo ọgọrun-un ọjọ ati mẹrinla lahaamọ awọn DSS naa.
Lọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, ti awọn DSS wọle ajafẹtọọ Yoruba nni, Sunday Igboho, ni Soka, n’Ibadan, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn, ti wọn si pa awọn eeyan nibẹ. Obinrin ti wọn n pe ni Amudat Babatunde yii lo dọgbọn ṣe fidio oniṣẹju mejila kan, nibi to ti n fibẹru sọrọ, to n ṣọrọ ọhun jẹẹjẹ pe ogun ti yi awọn ka nile Igboho o. Pe awọn DSS ti sọ ijangbọn buruku kalẹ, to si n jẹ kawọn eeyan mọ ohun to n ṣẹlẹ bi iro ibọn ṣe n dun lakọlakọ.
Eyi lawọn DSS ṣe ni ọtọ ni keesi tiẹ lọdọ ijọba, ti wọn ni Jamiu paapaa ni awọn nnkan ija ogun lọwọ, ọtọ si lẹjọ tiẹ naa.
Ṣugbọn ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n koro oju si ajọ DSS fun bi wọn ṣe n fa ọrọ yii gun. Ohun to n lọ loju ayelujara bayii ni pe niṣe nijọba yii n fẹtọ awọn eeyan yii du wọn, ti wọn n rẹ wọn jẹ ti wọn si tun fi n han wọn.
Awọn eeyan n sọ pe ijọba Buhari jẹbi Sunday Igboho ni gbogbo ọna pẹlu awọn DSS to wọle rẹ naa, awọn ti wọn si tun ko nibẹ laiṣẹ ni wọn tun n foju wọn gbolẹ lẹyin ọpọlọpọ iya ti wọn ti fi jẹ wọn latimọle yii, wọn ni ko jọ pe ijọba yii bẹru Ọlọrun rara.