Awọn Ọmọọba binu si lemọọmu agba Ogbomọṣọ, wọn lo ṣe ohun tẹnikan ko ṣe ri  

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi ọrọ wahala lori oye lemọọmu agba ilu Ogbomọṣọ ti ṣe n ja ran-in-ran-in nilẹ lati oṣu meloo kan bayii, eyi to mu ki awọn aṣaaju ẹsin Isilaamu niluu ọhun ti mọṣalaṣi nla ilu naa pa laipẹ yii, awọn ọmọọba ilu yii ti sọ ọ ni gbangba fun gbogbo aye pe Ṣọun Ogbomọṣọ lo ni mọṣalaṣi nla ilu naa, bo tilẹ jẹ pe Ọba Ghandi Ọlaoye to wa nipo gẹgẹ bii Ṣọun Ogbomọṣọ bayii ki i ṣe Musulumi, to jẹ agba pasitọ ni i ṣe ninu ijọ Ridiimu.

Awọn mọgaji lati idile maraarun to n jọba niluu Ogbomọṣọ, ni wọn sọrọ naa ninu ipade oniroyin kan ti wọn ṣe ninu aafin Ṣọun, niluu Ogbomọṣọ, l’Ọjọruu, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Awọn mọgaji ọhun, ti gbogbo wọn jẹ ọmọọba ni: Ọmọọba Lamidi Itabiyi, to jẹ Mọgaji idile Aburúmákùú; Sikiru Oyelami, (idile Gbágun);  Ọlawọle Ọlaoye (idile Laoye); Oyebamiji Oyedeji, ẹni to ṣoju idile Bọ́làńtà; ati Ọmọọba Ọlayọde, ti i ṣe Mọgaji idile Ọdunaro.

Wọn ni wahala ti Imaamu agba ilu naa, Sheik Teliat Ayilara, n koju lori ọrọ oye ọhun bayii ki i ṣe ẹbi Ọba Ghandi Laoye ti i ṣe Ṣọun Ogbomọṣọ, bi ko ṣe lati idile Ayilara, ti i ṣe idile ti oun funra rẹ ti jade wa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn ọmọ idile kan ti wọn n pe ni Ayilara, niluu Ogbomọṣọ, lọpọn sun kan bayii ninu awọn idile to n jẹ lemọọmu agba ilu naa lati joye ọhun lasiko yii.

Ṣugbọn awọn aṣaaju idile Ayilara sọ pe Teliat, to n kirun fun wọn ni mọṣalaṣi nla Ogbomọṣọ, to wa ni Ọja-Igbo, nigboro ilu naa gẹgẹ bii Imaamu agba wọn ki i ṣe ẹni ti ofin ati aṣa ilu Ogbomoṣọ faaye gba lati wa nipo ọhun, nitori ọkunrin naa ki i ṣe ojulowo ọmọ idile awọn.

Ninu ipade oniroyin ti wọn ṣe laafin Ṣọun lọjọ Tọsidee ọhun ni wọn ti fẹsun nla kan Sheik Teliat, wọn lo n tabuku ilu Ogbomọṣọ, o si n gbiyanju lati fa aṣọ iyi Ṣọun Ogbomọṣọ ya pẹlu bo ṣe pe ọba ilu ọhun lẹjọ si kootu, to si n sọrọ àlùfàǹṣá nipa ọba nla naa.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe Kirisitẹni l’Ọba Ghandi to wa lori apere ọba lọwọlọwọ, sibẹ, oun lo ni mọṣalaṣi nla ilu naa, to jẹ bii ọfiisi tabi ori aleefa Teliat, nitori ọba lo ni gbogbo mọṣalaṣi nla ilu gẹgẹ bo ṣe wa niluu Iwo, Ọyọ, Ibadan, ati kaakiri ilu gbogbo to wa nilẹ Yoruba, to sì jẹ pe awọn ni wọn n fi lemọọmu agba ilu koowa wọn jẹ.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade ọhun, Mọgaji idile Gbágun, Ọmọọba Sikirulai Oyeyiọla Oyelami, ṣalaye pe, “Lati ọdun 1818 ti wọn ti n joye Imaamu agba ilu Ogbomọṣọ, Ṣọun lo maa n fi wọn jẹ ẹ, imaamu kẹtala si ni imaamu to wa nibẹ bayii. Gbogbo aṣẹ ti wọn ba si n pa ninu mọṣalaṣi nla to jẹ mọṣalaṣi ilu yii, ọdọ ọba lo ti maa n wa, koda bo ṣe ri ree lasiko ti ọba to wa lori itẹ ki i ṣe Musulumi.

“Iwọ (Teliat) waa lo o joye imaamu, o waa ni Ṣọun kọ lo fi ọ jẹ ẹ. Eyi lodi si aṣa ati iṣe wa niluu Ogbomọṣọ. Ati pe eewọ ni ki ọmọ ìlú Ogbomọṣọ gbe Ṣọun lọ sí kootu”.

Ninu ọrọ tiẹ, aṣoju idile Ọdunaro, niluu Ogbomọṣọ, Ọmọọba Oyebamiji Oyedeji, ṣalaye pe, “Ogun idile gan-an lo n ja a (Ìmáàmù agba Ogbomọṣọ) bayii, wahala to wa laarin oun atawọn ẹbi ẹ lo yẹ ko yanju, ki i ṣe lati maa darukọ Kabiesi si ọrọ ti ko kan wọn. Ọba ko ṣaa tun le joye laarin ilu, ẹnikẹni ti idile ba fa kalẹ lọba yoo faṣẹ si.”.

“Awa idile maraarun ṣepade alaafia pẹlu Teliat laipẹ yii. Nibẹ la ti tọka si aiṣedede rẹ fun un, paapaa, nipa bo ṣe sọ pe Ṣọun kọ lo fi oun joye, ati bo ṣe pe Aarẹ-Ago, to jẹ ijoye Kabiesi lẹjọ. O tọrọ aforijin, o kọwe ẹbẹ si wa, o si gbe ẹjọ naa kuro ni kootu gẹgẹ ba a ṣe gba a nimọran nigba naa.

“Ṣugbọn o ya wa lẹnu pe lẹyin naa lo tun lọọ pẹjọ mi-in si kootu. Nigba ti yoo tiẹ waa tun fọba le e, Ṣọun gan-an lo pe lẹjọ lọtẹ yii. Ṣe ẹ ri i pe ọrọ ọkunrin yii paayan lẹẹrin-in, abi nigba ta a sọ pe ko tọna fun ọ lati pe ijoye ọba lẹjọ, to o fi ijoye silẹ, to o waa kuku pe odidi ọba gan-an lẹjọ.

“Ohun to n dọgbọn sọ fun awa ọmọọba bayii ni pe mo ti pe baba yin lẹjọ, o ya, ẹ ṣe nnkan tẹ ẹ ba fẹẹ ṣe.”

Awọn mọgaji idile ọba maraarun niluu Ogbomọṣọ waa kilọ fun Sheik lati jawọ ninu ọrọ abuku to maa n sọ kaakiri nipa Ọba Ọlaoye, nitori ọba naa ki i ṣe ẹlẹsinmẹsin tabi ẹlẹyamẹya, bi alaafia ati iṣọkan yoo ṣe jọba laarin gbogbo eeyan to fi ilu naa ṣebugbe lo jẹ ẹ logun, lai fi tẹsin tabi ẹya ṣe.

Akitiyan ALAROYE lati gbọ tẹnu Sheik Ayilara lori ọrọ yii ko seeso rere pẹlu bi akọroyin wa ṣe pe lemọọmu agba yii lẹẹmẹrin ọtọọtọ, ṣugbọn ti ko gbe e, ti ko si
pe pada.

Leave a Reply