Awọn ọmọọba yari, wọn nijọba ko gbọdọ fipa yan alaga ẹgbẹ APC Ọṣun gẹgẹ bii Ọwa Igbajọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Idile ọlọmọọba Ọwa Iloro (Agbọn), niluu Igbajọ, nijọba ibilẹ Boluwaduro, nipinlẹ Ọṣun, ti kegbajare pe awọn alagbara kan ti fẹẹ lo ọgbọn aparutu lati fi alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọọba Gboyega Famọdun, jẹ ọba ilu naa.

Ninu lẹta kan ti wọn kọ si Gomina Gboyega Oyetọla, awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ rẹ, pẹlu adajọ agba nipinlẹ Ọṣun, ni wọn ti sọ pe awọn eeyan naa fẹẹ ko ijọba ati ileeṣẹ eto idajọ ni papamọra lati fi Famọdun jẹ Ọwa Igbajọ, eleyii to si lodi si nnkan ti awọn araalu fẹ.

Ọdun 2020 ni ipo Ọwa ti Igbajọ ṣi silẹ, lẹyin ti Ọba Olufẹmi Faṣade, Akẹran Kẹrin, waja.

Gẹgẹ bi lẹta ti olori ile Ọwa Iloro, Oloye Aderẹmi Adeifẹ Latilọ ati adele akọwe wọn, Ọmọọba Taye Abọdunrin, fọwọ si ṣe sọ, ile naa ti gbe ẹjọ to ni nọmba HIK/10/2021 lọ siwaju ile-ẹjọ giga ilu Ikirun, lati fidi rẹ mulẹ pe idile naa lo kan lati fa ọmọ oye kalẹ.

Wọn ni latigba ti ẹjọ naa ti bẹrẹ, ko si idaduro rara, awọn si ti lọ si kootu fun igbẹjọ lẹẹmẹrin. O ni Onidaajọ Jide Falọla lo kọkọ n gbọ ẹjọ naa ki wọn too gbe e kuro lagbegbe naa, to si mu ki Onidaajọ Onibokun maa gbọ ọ, titi ti wọn fi gbe oun naa kuro.

Wọn ni, “Iwaju Onidaajọ Adeleke ni ẹjọ yii wa bayii, o si ti fun wa ni ọjọ igbẹjọ miiran si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii. Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun wa lati gbọ laipẹ yii pe awọn alagbara kan ṣepade niluu Oṣogbo, nibi ti wọn ti fi da Ọmọọba Gboyega Famọdun loju pe oun ni yoo jẹ ọmọ-oye fun ipo Ọwa Igbajọ.

“Wọn sọ nibẹ pe gbogbo ọna lawọn yoo gba lati ri i pe awọn fa Famọdun kalẹ kijọba yii too kuro lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii. Koda, ṣe lawọn eeyan agboole rẹ ni Ọwa Oke-Ode n jo kaakiri ilu lọjọ naa pe ipo ti ọmọ awọn wa lo fa oriire naa fawọn.

“Bayii la bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mọ ọna ti wọn fẹẹ gbe aparutu yii gba, o si jọ wa loju lati gbọ pe adajọ agba nipinlẹ Ọṣun ti gba faili ẹjọ wa lọwọ Onidaajọ Adeleke ti ile-ẹjọ giga ilu Ikirun, lati gbe e fun ẹlomiiran lai sọ idi kankan pato.

“Idi ti wọn ṣe fẹẹ gbe ẹjọ naa fun adajọ miiran ti ko si lagbegbe wa ko ṣẹyin lati fi ṣe ojurere fun Famọdun to jẹ alaga ẹgbẹ APC Ọṣun lọ. Idi ni pe ki i ṣe pe Onidaajọ Adeleke wa ninu ọlude tabi o n ṣaarẹ.

“A wa n ke si ijọba lati ma ṣe gba ki ẹnikẹni lo wọn lati ṣe ohun to ta ko ifẹ ọkan awọn araalu, nitori ki i ṣe gbogbo igba lo yẹ kijọba maa fi agbara tẹ ifẹ ọkan wọn lọrun lori araalu.

“Ijọba ko gbọdọ fun ẹka eto idajọ laṣẹ lati tete gbọ ẹjọ kiakia lori ọrọ Ọwa Igbajọ lẹnu iwọnba asiko to ku ti wọn yoo lo lori aleefa”.

Leave a Reply