Gbenga Amos, Abẹokuta
Ni nnkan bii aago mejia oru Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla yii, ni awọn ọmọọta kan lọọ sọna si ofiisi ajọ eleto idibo to wa ni Iyana Mọṣuari, Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
ALAROYE gbọ pe inu buredi ni wọn da epo si to n rin gbindin gbindin si, bẹẹ ni wọn si fo fẹnsi wọnu ofiisi ọhun. Ni wọn ba ju awọn buredi ti epo ti wa ninu rẹ yii kaakiri awọn igun kọọkan ọfiisi naa, ni wọn ba sọna si i.
Ki oloju si too ṣẹ ẹ, ina naa ti ran kaakiri inu ọgba yii, o si jo ọpọlọpọ nnkan nibẹ.
Ọkan ninu awọn ọdẹ to n ṣọ ọfiisi naa, Azeez Hamzat, lo pe awọn panapana, ti awọn yẹn si wa sibẹ ni nnkan bii aago kan kọja diẹ. Ṣugbọn ina naa ti ṣọṣẹ. O ti ba awọn ọfiisi kan jẹ. Lara rẹ ni awọn ile ikẹru-si to wa nibẹ, ọfiisi awọn ọga ti wọn n ṣeto iforukọsilẹ ati gbọngan ipade to wa nibẹ.