Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ lawọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro nilẹ yii ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), pẹlu iranlọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa ti sọ pe awọn ṣi n wa gbogbo awọn ọmọọta kan ti wọn lọọ koju awọn oṣiṣẹ ajọ naa lasiko ti wọn n ṣiṣẹ wọn lagbegbe Odunze, ni Mile 3, niluu Diobu, nipinlẹ Rivers lọhun-un.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, Fraide, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ni wahala nla bẹ sile laarin awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA ọhun pẹlu awọn ọmọọta naa, nigba ti wọn fẹẹ mu ọkan ninu awọn to n gbe oogun oloro torukọ rẹ n jẹ Izuu Isuofa, tawọn eeyan tun mọ si ‘50’, to jẹ olori awọn oniṣowo egboogi oloro lagbagbe naa lọ.
ALAROYE gbọ pe gbara tawọn oṣiṣẹ NDLEA yii de sagbegbe naa ni wọn ti lọọ fọwọ ofin mu ‘50’ nibi to wa pẹlu ọpọlọpọ egboogi oloro to n ta ti wọn ka mọ ọn lọwọ. Niṣe ni wọn ko ma-mu-gaari si i lọwọ, ni wọn n ba taari rẹ lọ sidii mọto ti wọn paaki sitosi Ikwerre, lagbegbe Iheoma, wọn fẹẹ maa gbe e lọ. Lasiko naa ni awọn janduku kan ti ko sẹni to mọ ibi ti wọn ti wa ati ẹni ti wọn n ṣiṣẹ fun, ṣadeede ya bo wọn, ti wọn si n lẹ wọn lokuta, bẹẹ ni wọn n lu wọn, ti wọn si fiya oriṣiiriṣii jẹ wọn. Eyi to fa a ti ọpọ lara awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA naa fi farapa yanna-yanna lakooko akọlu ọhun. Nigba ti wọn yoo si fi pe awọn ẹlẹgbẹ wọn fun iranlọwọ, wọn ti lu ọn ṣe leṣe, bẹẹ ni awọn janduku yii ti ja ‘50’ gba kuro lọwọ, wọn si gbe ọkunrin naa pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ to wa lọwọ rẹ, pẹlu gbogbo egboogi oloro ti awọn ajọ naa ka mọ ọn lọwọ, ni wọn ba sa lọ patapata.
Ajọ NDLEA ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe loootọ lawọn janduku kan ti iye wọn ko lonka kogun ja awọn oṣiṣẹ ajọ naa, ti wọn si ṣe awọn oṣiṣẹ kan leṣe. Alukoro eọn nipinlẹ Rivers, Ọgbẹni Emmanuel Ogbumgbada, ṣalaye fawọn akọroyin niluu Portharcourt pe loootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe Odunze, ti wọn si ṣe awọn eeyan awọn leṣe gidi gan-an. Wọn tun tu ọdaran ti wọn n pe ni 50 silẹ, ti wọn si tun ko gbogbo egboogi oloro ti wọn gba lọwọ rẹ sa lọ patapata.
ALAROYE gbọ pe aṣẹ ti wa latoke bayii pe ki awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA naa ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lati tun lọọ fọwọ ofin mu ‘50’ pẹlu gbogbo awọn ọmọọṣẹ rẹ ti wọn kopa buruku ninu ọrọ naa.
Ọga agba patapata fun ajọ NDLEA nipinlẹ Rivers, Ahmed Mamuda, ti rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ajọ naa nipinlẹ ọhun pe ki wọn ma ṣe jẹ ki ohun to ṣẹlẹ naa ko irẹwẹsi ọkan ba wọn. O tun rọ wọn lati wa gbogbo ọna pata lati tun lọọ fọwọ ofin mu ‘50’ pẹlu gbogbo awọn ọmọọṣẹ re yooku, ki wọn le foju bale-ẹjọ.