Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn ẹlẹsin abalaye ti rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ya ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdọọdun sọtọ gẹgẹ bii ayajọ ọdun iṣẹṣe, ki ọjọ naa si jẹ ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun gbogbo awọn ara ipinlẹ naa pata.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun yii, alaga ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe, Mọgaji (Ọmọwe) Fakayọde Fayẹmi Fatunde ati Taiwo Fagbohun, to jẹ alukoro ẹgbẹ naa gboṣuba fun awọn aṣofin ipinlẹ Ogun fun bi wọn ṣe ya ọjọ kan sọtọ fun ayajọ ọjọ iṣẹṣe.
Lati bii ọdun meloo kan sẹyin lawọn oniṣẹṣe ti gbe aba naa lọ siwaju awọn aṣofin lawọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba pe ki wọn ṣofin ti yoo ya ọjọ kan sọtọ gẹgẹ bii ọjọ isinmi lati fi maa ṣami ayajọ awọn ẹṣin ibilẹ Yoruba, ṣugbọn ti awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin to ti kọja ko gbe igbesẹ gidi lori abadofin naa.
Ni bayii ti ileegbimọ awọn aṣofin ipinlẹ Ogun ti gba aba naa wọle, ti wọn si ti ya ogunjọ (20), oṣu Kẹjọ, sọtọ fun ayajọ ọjọ iṣẹṣe ni ibamu pẹlu ibeere awọn ẹlẹsin ibilẹ, ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe ti waa gboṣuba fun igbimọ awọn aṣofin ipinlẹ Ogun ati ijọba ipinlẹ naa lapapọ fun bi wọn ṣe gba ibeere awọn wọle.
Wọn waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati gbe iru igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ogun gbe yii. Ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ yii ṣalaye pe, “Ibeere wa lati jẹ ki gbogbo ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdọọdun wa fun ayajọ awọn ẹṣin ibilẹ Yoruba, ni ibamu pẹlu ofin orile-ede yii to faaye gba ẹnikẹni lati ṣẹsin to ba wu u, niwọn igba ti iru ẹsin bẹẹ ko ba ti ṣakoba fun ẹtọ ẹlomin-in.
“A fi asiko yii rọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ẹni ti ijọba rẹ ti mu ọpọlọpọ ayipada rere ba ipinlẹ Ọyọ, lati wo awokọṣe ipinlẹ Ogun nipa yiya ogunjọ, oṣu Kẹjọ, sọtọ fun ọjọ isinmi ayajọ ọjọ Iṣẹṣe lọdọọdun gẹgẹ bii ọjọ isinmi ṣe wa fun ọdun awọn ọmọ iya wa ti wọn jẹ Musulumi ati Kirisitẹni.”.