Ibrahim alagunmu Ilorin
Pẹlu ibọn ati oogun abẹnugọngọ ni awọn onifayawọ irẹsi dena de awọn asọbode nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ṣe akọlu si wọn, ASCI Saheed Aweda, ku lasiko akọlu naa, awọn mẹta miiran si fara pa yanna-yanna.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro asọbode ni Kwara, JBPT, Chado Zakaria, fi sita niluu Ilọrin, ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo ti salaye pe lasiko ti awọn ẹsọ naa n yide kiri ẹnu ibode l‘Opopona Sinau-Kenu, nijọba ibilẹ Baruten, ni awọn janduku onifayawọ naa dena de wọn pẹlu awọn ohun ija oloro bii ibọn, ada, oogun ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn si sekupa ẹni kan, ti awọn mẹta miiran si fara pa. O tẹsiwaju pe ajọ naa ri baagi irẹsi ogoji (40), ti awọn fayawọ naa di silẹ, ti wọn si sa lọ gba lọwọ wọn.
O ni wọn ti sinku ASCI Saheed Aweda, ni ilana ti Musulumi, lagboole wọn to wa ni agbegbe Popogbona, niluu Ilọrin, ti awọn mẹta to fara pa si ti n gba itọju to peye nileewosan bayii.